Oònirìsà sòrò nípa bí àwon èèyàn se n so kiri wípé èjè ni olorì tuntun tè mólè.
Oònirìsà ti jé kí á mò wípé yèyélúwà kò te èjè mólè rárá àti wípé Osùn ni Oluwaseyi Moronke, Yèyélúwà tuntun tè mólè kìí se èjè rárá.
Oba Adeyeye Enitan Babatunde omo Ogunwusi ti jé kí ó di mímò wípé èkejì efun tí a mò sí osùn ni olorì tè mólè, kí àwon èèyàn dáké kóntan kòntan tí won n so kiri.
Gégé bí a ti mò wípé àwon ìgbésì kòòkan wà tí èèyàn yóò gbé kí obìnrin náà tó wolé, ètóyí ni won se fún Yèyélúwà tuntun ooo.
Tagged with: Àṣà Yorùbá