Olayemi OlatilewaOwo awon olopaa digboluja ti a mo si Special Anti Robbery Squad (SARS) ti ipinle Kogi ti te ogbologbo olori awon adigunjale afurasi kan ti n lo ijapa gege bi ohun amusagbara lati fi sise ole jija.
Nasim Aliu to je olori awon ole ti won ti pa aimoye awon eniyan lekun jewo wi pe ogun ti won ba oun se, ara ijapa ni won se si.
Gege bi oro okunrin to wa lati ileto kan ti won pe ni Agheva Obehira to wa ni ijoba ibile Okehi se so, o ni ijapa yii loun maa n ba soro nigba ti oun ba fe lo digunjale nigboro.
“Ti mo ba ti fe jade lo sise, ijapa yii ni maa koko ba ni gbolohun. To ba ti ni ki n maa lo ko ni sewu, a je wi pe ode yoo dun nu-un. Opo igba ni mo si maa n gbe e korun ti mo ba fe lo sode to gbona. Ti ijapa naa ba wa lorun mi, ko si ota ibon to le wole si mi lara”, Nasim se bee lalaye
Komisanna awon olopaa ti ipinle Kogi, Ogbeni Emmanuel Ojukwu so wi pe, o ti pe ti Nasim ati awon isomogbe re ti n pa awon eniyan lekun saaju ki okete to boru mo o lowo. Ogbeni Ojukwu ni awon oju ona masose Lokoja si Okene, Okene si Auchi to fi de Benin lo je awon oju ona ti awon igara olosa naa ti n fi okunkun se ise ibi.
Komisanna tun fi kun un wi pe, Nasim to je olori awon ole naa lo je okan lara awon elewon ti won sa lo ni ogba ewon Kotonkarfi ni nnkan bi odun meji seyin.
Nnkan bi ago meji oru ni awon olopaa topase Nasim lo sinu ile re to n gbe leyin ti awon kan ta ile ise olopaa lolobo. Awon olopaa so wi pe logan ti owo te olori awon ole naa ni awon omo eyin re ti won mbe ni agbegbe naa ti na papa bora.
Ibanuje gori okan Nasim leyin to ko sowo awon olopaa. O bu omije loju, o yiju si ijapa re, o si n ba a soro pelu omi ekun kikoro.
“Iwo ijapa yii, o si le so fun mi wi pe awon olopaa ti detosi ile mi. Nasim boju woke bee lo tun wi pe, “a se looto ni oro awon agba wi pe, ‘ojo gbogbo ni tole, ojo kan pere ni toloun'”.
Ile ise olopaa salaye fun IROYIN OWURO pe, iwadii si n tesiwaju lati mu gbogbo awon alajosisepo Nasim ati awon igi-leyin-ogba re. Ju gbogbo re lo, awon olopaa ni laipe ni Nasim yoo lo foju bale ejo.