Home / Àṣà Oòduà / Oriki Ibeji

Oriki Ibeji

Wíníwíní lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀,
Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún,
Ẹdúnjobí,
ọmọ a gbórí igi rétẹréte,
Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá,
Ọ́bẹ́kíṣì bẹ́kéṣé,
Ó bé sílé alákìísa,
Ó salákìísà donígba aṣọ.
Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ.

Bi Táyélolú ti nló ni iwájú,
Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn,
Táyélolú ni àbúrò,
Kehinde ni ẹ̀gbọ́n,
Táyélolú ni a rán pé kí o ló tó ayé wò,
B’ayé dára , bi ko dára

O tọ́ ayé wò,
Ayé dun bi oyin
Táyélolú, Kehinde, ni mo ki
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀
O dé ilé ọba tẹ̀rín-tẹ̀rín,
Jẹ́ kí nrí jẹ, kí n rí mú.

Orí mí jẹ́ ń bí ìbejì l’ọ́mọ,
èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó ń w’ojú rẹ ní ọmọ gbajúmọ̀ bí ìbejì bí oooo…

àṣẹ
c: Ede Yoruba ti o rewa…
Aremo-Oba Bc Lawal
IyaOgbe OmoEdu Yeyelufe Oyewole

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...