#Our5K ti da wahala sile lori ayelujara: Ile Igbimo Asofin ni wahala naa ti bere
Olayemi Olatilewa
Lojo Wesde to koja yii nile igbimo asofin agba to kale siluu Abuja gbegi dina sisan owo egberun marun-un fun awon odo ile Naijiria ti ko nise lowo.
Abadofin eleyii ti asofin Philip Aduda (PDP, FCT) gbe si iwaju ile igbimo lo tile wa tele ninu awon ileri ti Aare Muhammadu Buhari se ni akoko ipolongo idibo re.
Sugbon ohun to jo ni loju ni bi o se je wi pe awon asofin omo egbe APC, ti won je omo egbe kan naa pelu Aare Buhari lo tun wa tako abadofin naa.
Isele to waye naa bere si ni ko awon omo Naijiria lominu, nigba ti opo si gba wi pe ise ti a ran iko niko n je. Ise ti Aare ati egbe APC ran awon asofin re naa ni won musa loogun
Opolopo awon odo ni won tu si ori ero Twitter pelu akori oro #Our5k, ti kaluku won si n so edun okan won pelu bi ijoba Buhari se fe fi ona alumonkoroyi dena ileri to se.
Sugbon sa, akowe ipolongo fun egbe APC, Alaaji Lai Mohammed ni egbe APC ati Aare Buhari ko ni ye nipa ileri re lati san egberun marun-un owo naira fun awon odo ti ko nise lowo.
Gege bi alaye re, o ni alaparutu ni awon omo egbe PDP, ati wi pe awon ni won fe fi oro naa da surutu sile nipa dida ori oro naa kodo.
Lai Mohammed, eni ti won tun ti fonte lu gege bi okan lara awon ti yoo je minisita, so wi pe eto ni gbogbo nnkan. Eniyan gbodo jokoo na ko to nase, ki onitoun ma ba a fipako nale. O ro gbogbo odo wi pe ki won lo mokan bale, gbogbo ileri ti awon se pata ni yoo foju han laipe.
Onwoye nipa oro oselu kan, eni to gba lati ba akoroyin IROYIN OWURO soro lai safihan oruko re, so wi pe, o sowon ninu oloselu ti o mu gbogbo ileri to se ni akoko iponlogo se nikete ti agbara ba de owo re. O ni ki i se ile Naijiria nikan, bo se ri kaakiri agbaye nu-un.
Oloselu a maa so asodun oro ni akoko ipolongo idibo lati ni ero leyin bi oko akoyoyo.
Sugbon pupo ninu ileri won ni agbara won kii ka nigba ti won ba de ori oye. Nigba ti awon kan maa ye iru ileri bee sile ki opo le seku fun igbadun tara won nikan.
Orisun: Olayemioniroyin.com