Home / Àṣà Oòduà / Rogbodiyan Mile 12: “Won ja omo ikoko gba lowo mi” – Abiyamo

Rogbodiyan Mile 12: “Won ja omo ikoko gba lowo mi” – Abiyamo

Leyin rogbodiyan to be sile ni agbegbe Mile 12 to wa niluu Eko l’Ojobo ose to koja yii (03/03/16), okunrin kan ti oruko re n je Daniel Igba lo ti ke gbajari sita wi pe, awon kan ja omo gba lowo oun nigba ti wahala naa gbena kari. Ninu itaporogan to waye laaarin eya awon Hausa inu oja Mile 12 ati awon Yoruba ni Ogbeni Igba ti gbe padanu omo re, eni odun kan ati osu meje ti ko si le so pato ibi ti omo na wa bayii.

“Ile ni mo wa ni nnkan bi ago mewaa aaro nigba ti wahala naa wo inu adugbo wa. Mo sare gbe omo mi lati sawo ile lo. Sugbon bi mo se n salo ni awon eniyan naa sare tele mi leyin, won lemi ba, won si bere si ni na mi. Won fi ake sami lori ati lowo. Ni akoko yii, mo si gbe omo mi mora sibe naa. Bi mo se ni ki n tun dide ki n maa salo ni mo subu. Bayii ni won se ri omo naa jagba lowo mi. Lati igba naa, a ko ti ri omo wa. Iya re ko si nile ni akoko naa, o lo si ileewe,” Ogbeni Igba se alaye naa bee.

Ninu ija nla to waye yii ni aimoye emi ati dukia ti gbe sofo ko to di wi pe awon omo ologun ile wa to wa dawo rogbodiyan naa duro.

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...