Home / Àṣà Oòduà / Sunday Shodipe tí wà láhàámọ wa– Alukoro ọlọ́pàá Ọ̀yọ́

Sunday Shodipe tí wà láhàámọ wa– Alukoro ọlọ́pàá Ọ̀yọ́

Sunday Shodipe tí wà láhàámọ wa– Alukoro ọlọ́pàá Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sọ ọ̀rọ̀ kanranjágbọ́n afurasí Sunday Shodipe di ẹgbẹ̀rún ìsáǹsá tí wọn ò lè sá mọ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, bí ìròyìn tó ń tẹ̀wà lọ́wọ́ ṣe sọ ọ́ di mímọ̀ pé ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tẹ arákùnrin kan, Sunday Shodipe tó sá mọ́ wọn lọ́wọ́ láìpẹ́ yìí.

Shodipe jẹ́ afurasí tí wọ́n ti kọ mú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani tó ń wáyé láìpẹ́ yìí lágbègbè Akínyẹlé ní ìlú Ìbàdàn.

Kò tíì dájú ibi tí wọ́n ti rí i mú, ṣùgbọ́n alukoro ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Fádèyí Olugbenga ṣọ̀rọ̀, ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó tí wà lákàtà ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá.

Bí ẹ kò bá gbàgbé, ìròyìn jáde rẹpẹtẹ nígbà tí ọwọ́ kọ́ tẹ Shodipe tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún Kódà, àti ìgbà tó tún sá lọ mọ́ ọlọ́pàá lọ́wọ́, ìròyìn kò tíì tán nílẹ̀ títí di àkókò yìí.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, ó ti pẹ́ díẹ̀ tí Ìròyìn sọ pé afurasí ọ̀daràn yìí ló wà nídìí ikú ọ̀wọọwọ̀ọ́ tó ń wáyé lágbègbè Ìjọba ìbílẹ̀ Akínyẹlé nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo