Gbajúgbajà olórin ti orílè èdè Nìjíríà, Timi Dakolo ti pín àwòrán ìyàwó rè àti àwon omo rè méta ní ìlú London, ó ko síbè wípé “wón tun ti dé baba wón tún ti dé”.
Timi Dakolo ti ó jé omo bíbí ìlú Accra ní orílè èdè Ghana tí baba rè sì jé omo Bayelsa ìlú kan ní orílè èdè Nìjíríà, orúko rè a máa jé David tí ìyá rè sí jé omo bíbí orílè èdè Ghana, orúko òun náà a máa jé Norah, tí ó kú nígbà tí Timi wà ní omo odún métàlá(13).
Bí ó tilè jé wípé omo bíbí orílè èdè Ghana ni Timi jé, tí ó sì tún ní ìwé omo ìlú ti orílè èdè Nìjíríà lówó, kò f’ìgbà kan so rí wípé omo ìlú méjì ni òun .
Njé èyí kò rewà bí?