Home / Àṣà Oòduà / Yinka Ayefele ti pada sile orin: Keresimesi odun yii ma minringindin

Yinka Ayefele ti pada sile orin: Keresimesi odun yii ma minringindin

Yinka Ayefele ti pada sile orin: Keresimesi odun yii ma minringindin

Olayinka Joel Ayefele ti pada si yara agbara orin lati gbe orin tuntun jade fun awon ololufe re kari aye. Gege bi awon ololufe orin Gospel Tungba se mo, ti odun tuntun ba ti n sun mole ni Ayefele, eni ti aare ana, Goodluck Jonathan fi ami-eye M.O.N.dalola, maa n gbe awo orin tuntun jade.

Ogbeni David Adeboye, agbenuso fun Ayefele lo kede eleyii nigba to n salaye akitiyan ti alase ati oludari ile ise Fresh Radio n se lati te awon ololufe re lorun doba. Awo tuntun ti won ko ti kede akole re yii la lero wi pe yoo jade kii odun keresimesi to wole de.

Ayefele, eni ti awon kan tun feran lati maa pe ni OJA tun fi kun un wi pe alujo inu awo orin oteyii tun maa yato si ohun ti awon eniyan mo tele. Nitori wi pe ise ti yato, alujo si ti sun siwaju.

Olayemi Olatilewa

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Sanwo olu

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré Yínká Àlàbí Ile-iṣẹ Aṣẹ ati Iṣakoso Pajawiri ti Ipinle Eko sọ pe awọn ti setan lati dahun si awọn ipe pajawiri ni ipinlẹ Eko laarin isẹju marun-un pere.Olùdarí Àgbà fún ilé-iṣẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Femi Giwa, sọ èyí ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú awọn oniroyin ní ìlú Èkó.Giwa sọ pé àfojúsùn ilé-iṣẹ́ náà ni láti dín àkókò tó wà láàrín ìyè àti ikú kù nípa rírí dájú pé ìdáhùn náà wáyé láàrín ìṣẹ́jú ...