Home / Àṣà Oòduà / Kini ijoba n se nipa awon ti n se ayederu?

Kini ijoba n se nipa awon ti n se ayederu?

Orisun iwe Iroyin
Iroyin yii kii se tuntun, yoo si ti to bi osu kan o le die ti asiri awon to n se ayederu elerindodo Coca Cola ti jade. Sugbon iru awon iroyin bayii, a kan maa n gbo naa ni. To ba ya, ategun yoo fe koja lori won, a ko si ni gbo ohunkohun nipa re mo.
ayederu

Ibeere ti Olayemi Oniroyin n beere ni wi pe, iru ijiya wo ni won se fun awon ti won se iru ise bayii? Kini ijoba n se lati dekun ayederu nisise lawujo wa? Aimoye ayederu oogun oyinbo lo kungboro to n seku pa awon mekunnu ni joojumo.

Bakan naa lomo se sori ti a ba n so nipa fiimu agbelewo. Gbogbo igba ni awon to n se fiimu tiata n kigbe wi pe ere ise owo awon, awon ika eniyan lo n gbadun re. Bawo ni orileede se fe tesiwaju ti a ba n gbe iru igbe aye bayii?

Kini e lero wi pe ijoba lese? Iru ijiya wo ni ijoba le gbe kale fun awon ti won ba ba nidi iru ise buruku yii?

Olayemi Oniroyin maa dake nibi naa. Sugbon tewure ba bojuweyin, dandan ni yoo bu epe felepe.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...