EndSARS: Olórí ilé aṣojú-ṣòfin ní ìṣúnà 2020 gbọdọ̀ pèsè owó fún ASUU bí bẹ́ẹ́kọ̀…
Fẹ́mi Akínṣọlá
Olórí ilé asojú-sòfin nílẹ̀ wa, Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà ti sòṛọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó se kókó tó n wáyé nílẹ̀ wa, paàpá ìwọ́de EndSARS.
Gbàjàbíàmílà, ẹni tó sọ̀rọ̀ yìí nínú àkànse ọ̀rọ̀ tó báwọn aráàlú àtàwọn asojú-sòfin sọ níbi ìjókòó ilé asojú-sòfin tó wáyé lój̣ọ́ Ìṣẹ́gun, wá kéde àwọn ìgbésẹ̀ tó fẹ́ gbé lóti yanjú àwọn ìṣèḷẹ̀ náà.
Gbàjàbíàmílà ní lákọ̀ọ́kọ́, òun kò ní buwọ́ lu ètò ìsúná ọdún 2020 láì jẹ̀ pé ó pèsè owó ìrànwọ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí àwọn èèyàn tó jáláìsí lásìkò ìwọ́de náà.
Bákan náà ló ní òun kò ní buwọ́lu ètò ìṣúná ọ̀hún, tí kò bá pèsè owónàá fún ẹgbẹ́ ASUU láti wá ìdáhùn sí ohun tí wọ́n n bèèrè fún.
Olórí ilé asojú-sòfin ní ilé asòfin náà yóó tún ríi dájú pé ìjọba gbé ìgbésẹ̀ láti se àtúnṣe àti àtúntò àwọn iléẹ̀kọ́ gíga gbogbo nílẹ̀ wa, tí yóó fi bá òde òní mu.
Ó ní òun kò ní buwọ́lu ètò ìsúná náà, tí kò bá ya owó nlá sọ́tọ̀ láti se àtúnṣe àwọn iléẹ̀kọ gíga wa.
Kò tán síbẹ̀, Gbàjàbíàmílà tún ní òun yóó ri dájú pé òun kàn sáwọn mọ̀lẹ́bí àwọn èèyàn tó pàdánù ẹbí wọn lásìkò ìwọ́de EndSARS yìí, láti tù wọ́n nínú.
Ó fikún-un pé, Ilé asòfin yóó tún sakitiyan láti ríi dájú pé àbá òfin tó n se àtúntò sí ètò ìdìbò nílẹ̀ wa dòhun, lọ́nà àti pèsè ìdìbò tó mọ́yán lórí ní Nàìjíríà.
Olórí ilé asojú-sòfin tún fọwọ́ gbáyà pé àtúnṣe òfin ilẹ̀ wa yóó wáyé, èyí tí yóó mú kó dángájíá láti fìdí ẹ̀tọ̀ ọmọnìyàn múlẹ̀.
Bákan náà ló ní ilé asòfin yóó sisẹ̀ lórí ọna táwọn ẹkun kọọkan yóó fi máa se àkóso àwọn ohun álùmọ́ọ́nì tó wà ní ẹkùn wọn, gég̣ẹ́ báwọn ọmọ ilẹ̀ yìí ti n fẹ́.
Gbàjàbíàmílà wá korò ojú sí ìwà ta ni yóó mú mi táwọn ọlópàá ̣n hù, tó sì ní wọn kò ga ju òfin lọ lọ́nà kọnà, èyí tó bá sì tàpá sí òfin, ló yẹ kí ọ̀bẹ òfin bà.