Òní laó roko létí opón
Òla laó sákà lágbèrù
Kùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòni
Káyáa múlé pontí
Kámú òdèdè rokà
Káfi agbada dínran
Àwèje wèmu nípón omodé wòyí lójú
Òrìsà lópabuké tán
Lódákún sábaro nídìí
Omo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjo
Omo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjo
Ilé-ifón kògba obàtálá
Èlàgboro kògba òrìsà
Ojúgboro ni tàfín
Èlàgboro ni tòrìsà
Omi níti ojú-omi rúwá
Èròyà wáàpon
Èròyà wáàmu
Rúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkò
Erú kùnrin won nííjé bánakú
Erú bìnrin won nííjé wòrúkú
Dimúdimù aleìgbò
Okùnrin yàkàwú orí ìgbá
Ìgbá kòwó
Okùnrin yàkàwú kòsòkalè
Òní laóko igbó olú-kóókó-bojo
Òla laóko igbó olú-kóókó-bojo
Akogbó olú-kóókó-bojo tán
Apa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtí
Wónní kí ákun-un
Kágbé oríirè fún obanídòó ejèrùwà-ìlèkè
Kágbé gègè àyàarè fún obaléyò ajòòrí Omo ajorí emi gbára
Kágbé gegelúge ìdíirè fun olúléhùnpejìgá Omo iná abara húta òjò palami okà se yèrìyèrì
Enití nbá perí obanídòó orí gbogbo amón-on fówon iwéréré-iwéréré
Enití nbá perí obaléyò ajòrí àyà gbogbo amón-on jìnwón igìrìrì-igìrìrì
Ènìyàn tí nbá perí olúléhùnpejìgá ìdí won yíò món-on lu agbè yàba ikunkun-ikunkun
Ogun obanídòó niná
Teléyò loòrùn
Ogun olúléhùnpejìgá logun Oba tínkówon iróro-iróro
Àpagbé awo ojó díáfún ojó
Àràngbé awo òòrùn díáfún
Tóbádi ojókan soso òjò
Yíóborí egbegbèrún òdá
Tóbá pawón tan
Apogun won ibíti-ibíti
Adífáfún olófin àyàngbo-àsè
Èyítí wónní kósáré losí òkè ohùnkò
Kólorèé jáwé abílè tíkòníkú wá
Ikú kò ikú kògbodò pa babaláwo
Àìsè àjà gbonhun
Húnró gbonhun lésè oba òrìsà
Kínni óní kíbi óyè lórí awo ?
Èjì-òyè òtító nikú yè lórí awo
ÈJÌ-ÒYÈ.
Ikú kòní pawá ní rèwerèwe ooo
Tag: Ewi Toni
-

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni
-
Ewi Toni: Egbe APC iba oooo
Egbe buruku tin fi ebi Pani
Odaju egbe tio lanu talaka
Omo buruku wole iya re busekun loruko APC
Egbe alatako ekun oko PDP
Egbe buruku tin fiya je mekunu
Alujonu egbe tin Rin Loru ogonjo
Egbe odaju tin fun apayan nipo
Egbekegbe tin so eniyan di oloti
Egbe amunisin tin so alagbara di ole
Egbe alusi toso lai Muhammad di opuro agbaye
Egbe ofo Toko coronal wo Nigeria
Egbe abamo ti ki tele ofin.
Akuse egbe tin pin rice agolo Kan fun eniyan mewa
APC all people’s criminal
This is special gift from Lagos State governor olusola sanwo olu to the people of Egan alafia CDA. Alimosho local government area.Lati owo Hamzat Mujeeb Olawale

-
Ewi Toni: Toju Iwa Re Ore Mi
Toju iwa re, ore mi;Ola a ma si lo n’ile eni,Ewa a si ma si l’ara enia,Olowo oni ‘nd’olosi b’o d’ola.Okun l’ola; okun n’igbi oro,Gbogbo won l’o nsi lo n’ile eni;Sugbon iwa ni m’ba ni de sare’e.Owo ko je nkan fun ni,Iwa l’ewa omo enia.Bi o l’owo bi o ko ni’wa nko?Tani je f’inu tan e ba s’ohun rere?Tabi ki o je obirin rogbodo;Ti o ba jina si’wa ti eda nfe,Tani je fe o s’ile bi aya?Tabi ki o je onijibiti enia;Bi o tile mo iwe amodaju,Tani je gbe’se aje fun o se?Toju Iwa re, ore mi,Iwa ko si, eko d’egbe;Gbogbo aiye ni ‘nfe ‘ni t’o je rere.(ENGLISH TRANSLATION)(ENHANCE YOUR CHARACTER MY FRIEND)Continue after the page breakEwi Toni – 20.03.2016
Ojumo ti mo
Eda ti ji saye
Eda ti ko mose asela
Ka ji ni kutu hai
Ka gbegba pota
Iya Akanke nko
O ti re werenjeje
Baba Talabi da
O ti sare re kutuwenji
Ki ni n le wa?
A ni ki tie ni awa omo eniyan n ba kaye?
Atilowo lowo o fagbara
Atila o pile fa kirakita
Eda a sare owo titi
Ati roju founje bonu inira ni
Ani ati woso to gbajumo yoo deewo
Gbogbo pakaleke
Gbogbo furukankan furukankan
E jowo eyin omoran
Lori kini
Olowo to sare owo titi
TEdumare wa bola fun
To wa lowo ohun tan
Ti o le fara bale nawo
Gbogbo ere ti n sa ni pe:
Ki n lowo ju Lamorin
Bi mo lowo ju Lamorin
Ki n la ki n lu
Ju ti Baba isale oro lo
Sugbon igbagbe to salakan ti ko fi lori tomo
eeyan n ba ka
Ere aiku Lahun sa to fi dera e mo posi
Bo ba se po ranti ni
I ba ranti pe ibi gbogbo lowo iku de
Olowo to lowo tan
Ti ko le sinmi ara taare
Eekan laya n ri o soju losoose
Awon tile ti gba kadara kanpa
Ariwo owo nii pa kaye
Eda gbagbe wi pe
Aye la bowo
Bo pe bo ya
Owo taa ni lowo
Owo olowo kuku ni
Ka roju sare mo niwon
Mo fe lowo bi olowo kan oke ohun
Mo fe kole to lalewu
Mo fe jaye oloba
Bi I ti karuna
E da ranti pe
Ojo iku ba de
Ko kuku ni gbowo oya
Ojo tAlimuntu ba wole
Ko ni beere abetele
Olowo to lowo tan
Ko tun le fowo saanu
Se lo n wo talika bii ko ku
Talika gan-an n lowo bii koro re o danu
Ija olowo pelu talika
Adesoye Omolasoye Akewi irorun ni:
Boya ni o ni dorun alakeji ko to pin
E ni ti yoo laye
Bo ba n tewe dandan ni kowo de
Eeyan ti ko si yanri owo lodo alagbede orun
Bi wo fun in ni kokori ile owo
Yoo ju nu
Sare owo mo niwon ore wa
Awa o kuku ni o ma gbiyanju
Ki ni ko soko fonle
A ji le tente enu
Abete tipiri
A ji nasee le Gbalaja
Ounje rasirasi ni e fonle je
Emi o wi pe o ma sise
Akewi imora!
Ka sare ola mo niwonba
Laso imoran ti n fe lele lara ti wa
Gbogbo bo ti wu ka lowo to
A kuku ni mu eepinni de jinnisa.