Home / Àṣà Oòduà / Èèyàn tó pọ̀ ní Nàìjíríà kìí ṣe dúkìá, gbèsè ni – Sanusi

Èèyàn tó pọ̀ ní Nàìjíríà kìí ṣe dúkìá, gbèsè ni – Sanusi

Èèyàn tó pọ̀ ní Nàìjíríà kìí ṣe dúkìá, gbèsè ni…Sanusi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Emir ilu Kano, Mohammadu Lamido Sanusi (II) sọ oko ọrọ kan niluu Abuja lọjọ Aje nibi to ti sọ pe gbese ni iye eeyan to wa lorilẹ-ede Nàìjíríà bayii jẹ.
O ni nitori pe Naijiria ni ero to pọ ti awọn eniyan pọ pupọ ko sọ pe o ja si èrè fun wa.
Sanusi sọrọ yii nibi apero lori ọrọ aje ẹlẹẹkẹẹdọgbọn iru rẹ to n lọ lọwọ niluu Abuja.
Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayode Fayemi ati oludasilẹ ṣọọṣi Kukah Centre, Bisọbu Matthew Kukah naa wa lara awọn to peju sibi apero ọhun.
Emir Kano ṣalaye pe lootọ ni pe Nàìjíríà le ṣe ohun to pọ nitori iye eeyan to wa nibẹ ṣugbọn ko ri bẹẹ lasiko yii, pipọ t’eeyan pọ ni Nàìjíríà ko tii maa mu anfaani kankan ba orilẹ-ede naa bayii.
Sanusi ni ko tii si eto ti yoo jẹ káwọn ẹgbẹlẹgbẹ ọdọ wulo fún orilẹ-ede Naijiria lọjọ iwaju.
Sanusi sọrọ yii nibi apero lori ọrọ aje ẹlẹẹkẹẹdọgbọn iru rẹ to n lọ lọwọ niluu Abuja.
Emir Sanusi ni iṣẹlẹ ijinigbe, idigunjale, igbesunmọmi, ikọlu laarin agbẹ ati darandaran n waye nitori bi awọn eeyan naa ṣe n pọ si ni Nàìjíríà

.

Ó fikun ọrọ rẹ pe, bi èèyàn ṣe pọ to ni Nàìjíríà ko tii ṣe orilẹ-ede náà loore gẹ́gẹ́ bi ọpọ ṣe ro.
Sanusi ni Nàìjíríà ko tii dagba gẹ́gẹ́ bi orilẹ-ede de ibi ti àwọn èèyàn to wa nibẹ yoo jẹ́ dukiẹ fun un.
Sanusi gbamọran pe ki awọn eniyan Nàìjíríà naa maa ṣamulo ọpọlọ wọn si iwa daadaa ati aṣeyọri ninu imọ bii sayẹnsi lasiko yii.
Nibayii, awọn eeyan to wa ni Nàìjíríà din mẹwaa ni igba miliọnu .

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.