Home / Àṣà Oòduà / Esun idigunjale la o fi kan eni to ba gbegidina ti n gbowo odun” Olopaa Ipinle Ogun

Esun idigunjale la o fi kan eni to ba gbegidina ti n gbowo odun” Olopaa Ipinle Ogun

Komisanna awon olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abdulmajid Ali ti kede wi pe,ile ise olopaa ipinle Ogun ti wa ni imurasile lati gbogun ti iwa idaran to seese ko suyo lasiko poposinsin odun taa wa yii.
Ninu oro Ogbeni Abdulmajid, eleyii to se ni olu ileese olopaa to wa ni Eleweran niluu Abeokuta, ibe lo ti n ro awon ti won ba fe wuwa idaran lati kowo omo won baso nitori ileese olopaa ipinle naa yoo wa loju ise losan ati loru.
Bakan naa lo tun fi kun wi pe, awon ofin to de banger si wa sibe digbi, enikeni ti owo ba te yoo fimu danrin.
Ogbeni Abdulmajid tun salaye siwaju wi pe, iwa idaran gbaa ni ki awon kan maa gbegi dina lati gbowo odun tabi ki won maa ti popona pa nitori ayeye odun ti a mo si Carnival.
O ni awon nnkan bayii ni ileese olopaa ko ni faaye gba rara.
“Esun idigunjale, ni esun ti ile ise olopaa yoo fi kan enikeni ti owo ba te wi pe o gbegidina, to si n fi tipatipa gbowo odun lowo awon eniyan. Ile ise olopaa ipinle Ogun ko ni foju ire wo enikeni ti owo ba te rara,”  Ogbeni Abdulmajid fi kun alaye re bee.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo