Home / Aarin Buzi / Oba’binrin Asa Solaade Iyaasa: Ohun IFA ati Iwure

Oba’binrin Asa Solaade Iyaasa: Ohun IFA ati Iwure

ÒÒṢÀ ÒKÈ, ÌBÀ

IFA ni ti a ba ji a ki OLU
OLU moji mo ki o loni

IFA ni to a ba ji a ki Osin, osin moji mo ki o loni

ELA ni kan ni somo bibi inu Agbomiregun
Nigba to n ti ode orun bowa si ode isalaiye, ebo ni won ni kose

Won ni k’oru igunnugun ki ile aiye re o le bagun

Won ni k’oru Eye osin ko le ba di eni apesin
Won ni koru epo ela ko le ba la
Won ni koru Eran oya ki ibi gbogbo ko le baaya leyin re.

O gbebo nibe o si ru, emi naa ru temi oo

Emi ti ru igungun, ifa je ki ile aye mi k o gun
Emi ti ru eye osin, ifa Je ki ndi eni apesin
Emi ti ru epo ela, ifa je ki nba won la ni ode isalaiye

Emi ti ru eran oya, ifa je ki gbogbo aburu aye,ijamba ati gbogbo arun ko ya lẹyin mi.

Mo wa ṣe niwure wipe gbogbo wa la o dẹni apesin, a o ni bọjọ ọlọjọ lọ, igba ile wa a roju, awo ile wa a raaye, aiye o ni fẹgba fun wa lounjẹ oo, a o ni báwọn rajo alọide, awa ti a ri ibẹrẹ ọdun yii la o ri opin rẹ pẹlu ire gbogbo.

E ku ọjọ mẹta oo

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*