Home / Àṣà Oòduà / ORIKI ILORIN Ilorin afonja.

ORIKI ILORIN Ilorin afonja.

ORIKI ILORIN

Ilorin afonja enudunjuyo
Ilu to jinna s’ina
To sunmon alujana bi aresepa
Ilu tobi to yen,won o leegun rara
Esin l’egungun ile baba won
Akewugberu ni won
A s’adura gbore
Aji fi kalamu da won lekun arise kondu kondu
Won e lu lagbadu
Kewu ni won n ke
Eegun wa bura
Bo ba denu igbo ri
Paka wa bura
Bo ba d’igbale
Ero iwayiopo wa bura
Be o ba l’obirin
Ayidopo laya nle omo egbirin ote
Nile opo omo laderin
Opo korobiti ajagun ajase
Opo k’aja ka r’oyo naa
Abidesu ko je a wo eni to l’oba
Omo opo o gboro
Won pe n koju e s’ina
Ina o gboro
Won pe n koju e s’omi
Omi o gboro
Won pe n fi ponti to le
Oti to le o gboro
Won n f’omo to buru
Omo wo wa lo le tio gboro
Afonja o gboro
Ni won ba koju omo ponilewa s’ogun
Ogun naa l’afonja lo tio pada wa’nule mo
To fi lo te ilu Ilorin
Ilorin afonja ti nje enudunjuyo.

Ki eledua ma je ki ilu Ilorin kodaru lailai. Ase!!

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.