Home / Àṣà Oòduà / Ọ̀RỌ̀ ÌSÍTÍ

Ọ̀RỌ̀ ÌSÍTÍ

Húùm…ètò ìsèlú tiwa-ntiwa
kò yẹkí ó mú ìjà wá bí ó bá se wípé l’òtítọ́ la
n’ìfẹ́ ará ìlú l’ọ́kàn, k’ára ó leè dẹ t’ẹrú-t’ọmọ
yàtọ̀ sí ìsèlú bí-o-ba-o-pá, bí-o-kò-báa-kó- bu-
bùú-l’ẹ́sẹ̀, èyí tó wọ́pọ̀ l’órílẹ̀ èdè wa!!. Àwa
ọmọ mẹ̀kúnnù t’àwọn Olósèlú ń kó Ìbọn, Ọ̀kọ̀
àti Àdá fún nít’orí à ti dé’pò sin ìlú, kò sàì mọ̀
wípé àwọn àti mọ̀lẹ́bí wọn ǹ bẹ n’ípamọ́, tí
wọn ń f’apá Ewúrẹ́ j’iyán, tí àwa ọmọ
mẹ̀kúnnù wá ń pa ara wa nít’orí ẹgbẹ̀rún kan
ni??!!.
Ẹ̀yin alárá wa, bí àsìkò ìdìbò lá ti yan àwọn
Olórí tuntun bá dé, ẹ jẹ́kí a la’jú wa s’ílẹ̀
dáadáa, kí àwọn Ọ̀jẹ̀lú ó máse tún dá wa
pada s’óko ìya tàbí ẹ kò rí bí ara se ń ni
gbogbo wa ni??. K’Édùmàrè máse pe ti wa
n’íyà l’órílẹ̀ èdè wa mọ́ o!!.

About Lolade

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Osa Esu

Osalogbe Awo ApalaOsalogbe Awo ApalaaAdifafun Orunmila AjanaBaba Yoofi Oro jagbajagb’a ro Sorun EsuBabagbeboBabaruboEsu Odara ti n ba Ni Owo lowo Odorun re Esu Odara Odorun reEsu Odara ti n bani Aya Odorun re Esu Odara Odorun reTi n ba bimoTi n ba Ko ileEsuodara ti n ba ni EsinEsuOdara ti n ba Ni Ire Gbogbo Odorun reEsuOdara Odorun reRudurudukeeAdifafun Orunmila Ajana lojo ti Ire Gbogbo n’lo lojude Edu ti Okookan koyale waBabagbeboBabaruboRudurudukee Akara kan Soso Nimoyan fun Esu Ire Aje ...