Home / Àṣà Oòduà / Orunmila ni awure emi naa moni awure

Orunmila ni awure emi naa moni awure

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun ku isimi opin ose adura wa yio gba o, ori buruku koni je tiwa o ase.
Laaro yi mo nfe ki a mo iwulo ewe yi ninu odu ifa OSA ALAWURE, oruko ewe yi ni won npe ni ewe alukerese, ewe yi wulo pupo ninu odu ifa yi ati fifi we ifa, o je ewe ti a maa fi nwe ori ki ori naa baa le se rere laye ati lati we awon ibi ti ki nje ki ori eniyan gba ire danu.
Ifa naa ki bayi wipe:
Orunmila ni awure emi naa moni awure
Orunmila ni awure ni alara fi we ori omo tire ti omo tire di olowo
Orunmila ni awure emi naa moni awure
Orunmila ni awure ni ajero kinosa fi we ori omo tire ti omo tire di olola
Orunmila ni awure emi naa moni awure
Orunmila ni awure ni owa orangun aga fi we ori omo tire ti omo tire di oloro, ti won kole mole ti won ra ile mole
Moni Orunmila kilode ti o fi nfo bi ede ti o fi nfo bi eyo?
Orunmila loun ko fo bi ede o loun ko fo bi eyo, oni akapo toun loun nbawi wipe ki o lo we ori re ki o baa le di olowo, oloro ati olorire laye
Mo wani toba je biti akapo tire ni kini nkan to maa fi se ti yio fi di olorire laye?
Oni ki o lo ni ewe alukerese,…………ao gbo sinu Omi ao gbaye ifa naa si akapo naa yio fi fo ori re tabi ki a gun mose ki o maa fi we ori.
Eyin eniyan mi, mogbaladura laaro yi wipe eledumare yio bawa we ori buruku ori wa danu, ori buruku koni je tiwa ao jeeyan laye o, awure yio je funwa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 
English Version:

Continue after the page break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.