Home / Àṣà Oòduà / Oselu Kogi: “Idi ti a ko fi yan Faleke ni yii” – Alaga APC

Oselu Kogi: “Idi ti a ko fi yan Faleke ni yii” – Alaga APC

Alaga fun egbe oselu APC lapapo, Oloye John Odigie-Oyegun ti salaye idi pataki ti awon agba egbe naa fi pamopo lati yan Alhaji Yahaya Bello gege bi oludije ti yoo ropo Abubakar Audu, eni to jade laye saaju ki eto idibo naa to kesejari.

Ninu oro re, eleyii to se nibi ipade to ni pelu awon oloye egbe APC ti won je ti ekun Ila-oorun Kogi, o ni bi ayo olopon ni oselu je. Eleyii to gba arojinle ati ise opolo to fakiki.

“A ko gbodo yan enikeni to je wi pe yoo rorun fun egbe PDP lati ye aga mo nidi ni kootu leyin to ba di gomina. Idi ni yii to fi je wi pe a gbodo sora gidigidi ninu awon ipinnu wa.

“Nigba ti a ba n pate-pero, a gbodo ma wo sakun ohun to seese ko sele lojo iwaju, ati awon ona ti ota le gba yo si wa. Eleyii je koko, ki omi ma ba teyin wogbin wa lenu.

“Ti iru nnkan bayii ba sele, o daju wi pe inu apa kan ko le dun si igbese ti a ba gbe. Sugbon a ni lati ro tegbe na ki ifaseyin ma ba de ba wa. Leyin eyi, ise wa ni lati yanju aawo tabi ikunsinu to ba jeyo laaarin awon ti igbese naa ko ba dun mo ninu,” Oyegun se lalaye bee.

Ninu alaye to te Olayemi Oniroyin lowo, siamaanu egbe PDP lapapo ko sai tanna imole si awon oro kan to jewo wi pe omo Abubakar Audu, Mohammed Audu, ye ko ropo alafo ti baba re fi sile lo. Won ni ko sohun to buru ti Faleke ba je gomina, ki won si fi omo oloogbe se igbakeji re.

“O ye ko ye wa wi pe oselu kii se oye idile. Eleyii ti a n gbe ipo baba fun omo. Lotito, omo le je ninu ola baba re lagbo oselu. Baba si le tun ran omo re lowo ninu oselu. Koda, omo le goke agba ninu oselu nipase gbajumo baba re. Sugbon ki i sebi ka gbe ipo baba fun omo. Kosi ohun to jo bee ninu oselu,” Oyegun fi kun oro re bee.

Orisun: Olayemioniroyin.com

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.