Home / Awọn Iroyin Agbegbe / Ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo pe Ààrẹ Buhari lánàá , àmọ́ ń kò ri bá sọ̀rọ̀ – Sanwo-Olu
sanwo

Ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo pe Ààrẹ Buhari lánàá , àmọ́ ń kò ri bá sọ̀rọ̀ – Sanwo-Olu

Ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo pe Ààrẹ Buhari lánàá , àmọ́ ń kò ri bá sọ̀rọ̀ – Sanwo-Olu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tíì tán èèyàn ńlá kò ní tíì sinmi àròyé Sanwo-Olu tíí se Gómìnà wọn ní ìpínlẹ̀ Èkó tún ti gbóhùn sókè sàlàyé pé òun kò tíì rí ààyè bá Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, títí di àkókò yìí.

Ó ní òun pe Ààrẹ Buhari lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn náà láàrọ̀ àná, àmọ́ wọ́n ń bùn mi gbọ́ pé kò tíì dé sí ọ́fíísì.

Ó fikún un pé òun tún padà pè lórí aago, àmọ́ tí wọ́n sọ fún òun pé ó wà ní ìpàdé Ìgbìmọ̀ aláṣẹ Ìjọba ilẹ̀ yìí tó ń wáyé lánàá.

Bákan náà ni Sanwo-Olu ní olórí iléeṣẹ́ ọmọ ológun ilẹ̀ wa ti pe òun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ọ̀hún.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ọ̀hún tún sísọ lójú rẹ̀ pé ìjọba òun ti gbé igba mílíọ̀nù náírà kalẹ̀ bíi owó gbà má bínú fáwọn èèyàn tó forí sọta ìwọ́de EndSARS náà.

Ó wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ tó ń sèwọ́de láti fi orúkọ èèyàn méjì sílẹ̀, tí yóó ṣojú wọn nínú Ìgbìmọ̀ olùwádìí tí Ìjọba gbé kalẹ̀ lórí ẹ̀hónú wọn.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ní àsìkò tó tọ́ yẹ kí wọ́n fààyè gba àwọn ìpínlẹ̀ láti ní ọlọ́pàá tiwọn, Kódà, ó ní ọ̀rọ̀ náà ti pẹ́ jù.

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

endsars

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì fèsì lórí ìwọ́de EndSARS

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì fèsì lórí ìwọ́de EndSARS Fẹ́mi Akínṣọlá Ìjọba orílẹ̀-èdè United Kingdom, ti fèsì lórí ìwé ẹ̀sùn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fọwọ́ sí, tí wọ́n sì fi ránṣẹ́ síi. Ìwé náà ló ń ké sí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé tó wà nínú àjọ Commonwealth, láti fi ‘ ìyà’ jẹ àwọn Olórí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ìbáwí, fún ẹnikẹ́ni nínú wọn tó lọ́wọ́ nínú títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú, gẹ́gẹ́ bí òfin àjọ náà ṣe sọ. Ọmọ Nàìjíríà bíi okòólérúgba ó dín díẹ̀ (219,665) ...