Home / Àṣà Oòduà / Ọrẹ Fálọmọ , Irúnmọlẹ̀ Ìṣègùn Tó Dáńtọ́ Nínú Ìràn Oòduà(Yorùbá) Wọ Káàlẹ̀ Lọ

Ọrẹ Fálọmọ , Irúnmọlẹ̀ Ìṣègùn Tó Dáńtọ́ Nínú Ìràn Oòduà(Yorùbá) Wọ Káàlẹ̀ Lọ

Ọrẹ Fálọmọ , irúnmọlẹ̀ ìṣègùn tó dáńtọ́ nínú ìràn Oòduà(Yorùbá) wọ káàlẹ̀ lọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Hùn! Báakú làá dère,èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. Ni báyìí, gbogbo ọmọ Oòduà(Yorùbá) ló tí ń sun rárà ọlọ́kan ọ̀ jọ̀kan lẹ́yìn in Dókítà Ọrẹ Fálọmọ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí oníṣègùn M.K.O Abíọ́lá nígbà ayé rẹ̀.
Adarí ẹgbẹ́ Afenifẹre Ayo Adebanjọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sàlàyé pé iṣẹ́ ribiribi ní Ore Fálọmọ ti ṣe nínú ìràn Oòduà(Yorùbá), àti pé ìran Oòduà(Yorùbá) ti sọ ògo ńlá kan nù.
Adebanjọ fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí gbogbo ìran Oòduà(Yorùbá) jí gírí láti gbé ògo ìran rẹ̀ ga bi Ọrẹ Fálọmọ ṣe se nígbà ayé rẹ̀, papàájùlọ gẹ́gẹ́ bíi Dókítà Abiola, ó dúro ti Abíọlá gidigidi lásìkò ìsòro, kò kẹ̀yìn sí bí àwọn tó kù ṣe ṣe nígbà náà.


Ó fí kún-un pé àwòkọ́se rere ni Fálọmọ jẹ́ nígbà tó fi jẹ́ Ààrẹ àwọn ẹgbẹ́ Dókítà ní Nàìjíríà, àmúyangàn ni àsìkò rẹ̀ jẹ́ fún ìdarí rẹ̀ àti ipò tí ọ̀rọ̀ ìlera wà lásìkò náà.
Afẹnifẹre ní Dókítà Fálọmọ kìí ṣe ẹni tí ìràn Oòduà(Yorùbá) gbọdọ̀ gbàgbé ní kíákíá.

,A bí Dókítà
Oluwatamilore Fálọmọ lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án ọdún 1942 nílùú Minna tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Niger báyìí.
Ọ̀gbẹ́ni Fálọmọ lọ ilé ìwé alákọ̀bẹ̀rẹ̀ ní Baptist Primary School, ìjàyè láàrin ọdún 1948 si ọdún 1955.
Ilé ìwé girama Methodist Boys High School ní ìpínlẹ̀ Eko ni Fálọmọ lọ láàrin ọdún 1956 sí ọdún 1960.
Fálọmọ tẹ̀síwájú ẹkọ rẹ̀ nílé ìwé St. Andrew College, nílùú Dublin lórílẹ̀-èdè Ireland láàrin ọdún 1961 sí 1962 kí ó tó lọ kàwé ní “Royal College of Surgeons ní Ireland” láti ọdún 1962 sí 1968.


Ó tún padà sí ilé ìwé “Royal College of Surgeons” nílùú Dublin lọ́dún 1978.
Ọ̀gbẹ́ni Fálọmọ ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Folashade Ṣorunkẹ lọ́dún 1968.

Dókítà Fálọmọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nílé ìwòsàn Park Hospital, Davyhulme ní Manchester lọ́dún 1969 sí 1970.


Ó tún ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ètò ìlera ìpínlẹ Eko lágbègbè Surulrere lọ́dún 1971 sí 1972, kó tó lọ ṣiṣẹ́ ní Ilé ìwòsàn Ìjọba ní Ikeja lọ́dún 1972 sí ọdún 1973.
Dókítà Fálọmọ di olùdarí ilé ìwòsàn Oníkòyí Clinic ní Yaba lọ́dún-un 1974 sí 1979
Fálọmọ jẹ́ Alága ẹgbẹ́ àwọn Dókítà lọ́dún 1971 sí 1974, ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àwọn Dókítà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì àti orílẹ̀-èdè Ireland.


Ó ṣiṣẹ́ ní Ilé ìwòsàn Maryland Specialist Hospital fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Dókítà Fálọmọ jẹ́ Dókítà fún olùdíje fún ipò Ààrẹ lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ òsèlú SDP nínú ìbò Ààrẹ ọdún 1993 ní Nàìjíríà, MKO Abiola.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...