Home / Àṣà Oòduà / Owo te awon omo egbe okunkun niluu Ado-Ekiti

Owo te awon omo egbe okunkun niluu Ado-Ekiti

Olayemi Olatilewa

Awon akekoo meji ile iwe gbogbonise ti ijoba apapo (Federal Polytechnic) to kale si Ado-Ekiti ati maanu kan ti n tu foonu se ni agbegbe naa ni won ti ko lo si iwaju ile ejo Majisireeti pelu esun wi pe won je omo egbe okunkun paraku.
Awon akekoo oloju-ba-n-deru-bomo meji naa ni Efeotor Oghenemarhe, eni odun mejilelogun (22) ati Felix Olukanmi, eni ti ojo ori re je metalelogun (23). Eni to siketa won ti oun ki i se akekoo naa ni Adebusuyi Kolawole, eni odun metadinlogbon (27) ni iwadii awon olopaa fidi re mule wi pe won je omo egbe okunkun kan ti n je Klansman Secret Cult.

Gege bi sajeninti Olasunkanmi Bankole to je olupejo se n so fun onidajo. O ni awon kannakori yii ni owo te lojo ketalelogun osu kewaa odun yii nibi won ti n sise dudu owo won. Aimoye ohun ija oloro ni won si ka mo won lowo bi aake, ibon sakabula, obe ati awon ogun abenugongo ti won fi n sohun amusagbara.

Gege bi afikun Ogbeni Bankole, o ni aimoye awon ise buruku bi ifipabanilopo, ijaagboro, ipaniyan ati ole jija to ti n waye seyin ni agbegbe naa ni iwadii fi han wi pe o lowo awon omo egbe okunkun yii ninu.

Bakan naa ni Bankole ro ile ejo lati maa gba beeli awon odaran afurasi naa rara nitori wi pe o lewu fun alaafia awujo.

Ogbeni Bankole, eni to n soro pelu ohun akin niwaju onidajo Idowu Ayenimo ko sai menu ba ohun ti iwe ofin so nipa egbe okunkun. O salaye wi pe ori kerin, abala kinni ati ori kewaa abala (a) ninu ofin Ipinle Ekiti ti won se lodun 2002 ko faaye gba egbe okunkun rara.

Nigba ti awon odaran afurasi naa so fun ile ejo wi pe awon o jebi gbogbo esun ti ile ejo fi kan awon ati wi pe ko si otito rara ninu oro olufisun awon.

Onidajo agba ti ile ejo Majisireeti, Idowu Ayenimo sun igbejo naa siwaju di  ojo karun-un osu kokanla odun yii. Leyin eyin lo ni ki won da awon odaran afurasi naa pada si ogba ewon Federal Prisons to wa ni Ado-Ekiti.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo