Home / Àṣà Oòduà / Won Fadi Omo Odun Meji Ya Niluu Abuja

Won Fadi Omo Odun Meji Ya Niluu Abuja

Olayemi Olatilewa

Omokunrin eni odun merindinlogun (16) kan ti lo foju ba ile ejo niluu Abuja leyin asemase pelu omobirin, eni odun meji (2) kan.

Iroyin yii lo jade nigba ti olupejo, ogbeni  Adama Musa, eni ti n soju ile ise olopaa n se alaye naa niwaju ile ejo Gudu Upper Area Court to kale siluu Abuja.
Ogbeni Musa n so fun ile ejo wi pe, ogbeni Samuel Zakka ti n gbe ni abule Pegi to wa ni Kuje lo mu esun naa to ile ise olopaa wa lojo kejilelogun osu kesan-an odun yii.

Ogbeni Samuel Zakka lo salaye fun awon olopaa wi pe odaran naa tan omo re, eni odun meji lo sinu ile kan ti won on ko lowo eleyii to lo n ba omo naa se asemase nipa titi ika bo inu idi omodebirin naa.

Awon olopaa se iwadii oro yii, won mu omobirin kekere yii lo si ile iwosan fun ayewo lati mo okodoro oro. Abajade si fi ye won wi pe lotito ni asemase waye loju ara omodebirin naa.

Igba ti omokunrin odaran yii n duro niwaju ile ejo, oun to wi naa ni wi pe oun o jebi awon esun ti ile ejo fi kan-an.

Nibayii, Onidajo Umar Kagarko ti ni ki won gba beeli odaran naa pelu egberun lona ogorun owo naira(N100, 000) pelu oniduro to lokun-undi, to si tun je olugbe ilu Abuja. Nigba ti won sun igbejo naa di ojo ketadinlogun osu kejila odun 2015.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo