Home / Àṣà Oòduà / Adelabu tún gbé Ṣeyi Makinde lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Adelabu tún gbé Ṣeyi Makinde lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Adelabu tún gbé Ṣeyi Makinde lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí o bá nídíì,arúgbó ò gbọdọ̀ sunkún ọmú.
Bayo Adelabu ti ẹgbẹ́ òsèlú APC ní òun kò faramọ́ ìdájọ́ Àjọ Elétò Ìdìbò tó ní Ṣeyi Makinde ló wọlé nínú ìdibò tó kọjá.


Oloye Adebayo Adelabu ti ẹgbẹ́ oselu APC ti ni, òun kò faramọ idajọ ajọ eleto idibo to da igbẹjọ oun nù lórí idibo to gbe Ṣeyi Makinde wọle gẹ́gẹ́ bi gomina nipinlẹ Ọyọ. Lẹ́yìn ọjọ mọkanlelogun ti idajọ naa waye ni ilu Ibadan, ni Adelabu gbe ẹjọ lọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.


Adelabu ati ẹgbẹ oselu APC sọ wi pe, magomago waye ninu idibo Ọjọ Kẹsan, Osu Kẹta, ọdun 2019, eleyii to gbe Ṣeyi Makinde wọle gẹgẹ bi gomina.
Adelabu wa n beere lọwọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lati sọ wi pe oun lo ni ibo to pọju lọ ninu idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ọyọ abi ki wọn tun ibo naa di.
Tí a ko ba gbagbe, Alaga igbẹjọ naa, Justice Muhammed Sirajo salaye pe awọn da ẹjọ ti APC pe mọ Ṣeyi Makinde nu nitori gbogbo àwọn ẹlẹri ti Adelabu pèé kò ní ẹri tó daju, amọ ti wọ́n ń sọ ahesọ lásán.

Iroyinowuro

About Lolade

x

Check Also

seun kuti

Orí kó Seun Kuti yọ kúrò lọ́wọ́ ikú ní yàrá ìgbàlejò US

Mary Fágbohùn Olórin Afrobeat Seun Kuti ti fi ìrírí ibanuje ọkàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà han nígbà tí ọta ibọn kan gúnlẹ̀ lójú fèrèsé yàrá igbalejo rẹ̀. O salaye ibapade to ba ni lẹru naa lori oju-iwe Instagram rẹ, o fi fidio ferese ti ọta ibọn naa bajẹ ati iho re han. Seun, ẹni ti o ṣalaye iyalẹnu, beere iwoye ti aabo ni Amẹrika. Ninu fonran naa, Seun Kuti sọ pe oun wa ninu yara igbalejo, ti oun n sinmi, ...