Home / Àṣà Oòduà / “Ajo NFF kii ta agbaboolu soke okun” Aare NFF

“Ajo NFF kii ta agbaboolu soke okun” Aare NFF

Ogbeni Amaju Pinnick to je aare ajo ti n risi ere boolu alafesegba, Nigeria Football Federation, ti fesi lati tako awon aheso kan ti n lo nigboro wi pe, ajo NFF n se bisineesi tita agbaboolu soke okun.

O ni iro to jina si otito ni aheso naa. Ninu oro re, o ni oseese ki awuyewuye naa jeyo ninu asigbo oro ti minisita fun ere idaraya ati awon odo, Ogbeni Solomon Dalung so.

O ni minisita so wi pe ki awon se kia nipa awon eto awon fun awon agbaboolu abele ti won fe lo maa gba boolu ni awon ilu okeere.

“A wa kii ta agbaboolu si okeere, iwe eri lasan ni awa n fi le won lowo. Mo si gba wi pe awon ti won gbe iroyin naa kiri ko gbo alaye minisita ye yekeyeke ni. Minista ko so nipa tita agbaboolu, awon eto wa lati se iranwo fun awon agbaboolu abele ti won fe lo si oke okun lo ni ka se ni kiakia,” Pinnick se alaye naa bee.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo