Home / Àṣà Oòduà / APINTANBI

APINTANBI

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun Ku isimi opin ose eledumare koni jeki a fi eleyi se asemo o ase.
Laaro yi mo fe so die nipa oro APINTANBI ti awon opuro ati alainimo babalawo miran nsope ki nse oruko toye ki won maa pe iyawo awa babalawo niyen, ti won fe fi iwa imotara eni won ati ailoye won si opolopo eniyan lona latari ki won le loruko Lori ero ayarabiasa.
Won ni IYANIFA, IRE, IWA ati beebee lo ni o ye ki a maa pe oruko iyawo awa babalawo, iyanifa ki nse oruko rarara, ise eyemiwo ti obinrin miran nse ni won fi npe ni “IYANIFA” koda o le ma je APINTANBI ifa gan latari wipe ti oko re kii ba nse babalawo, awon oruko toku si je oruko apenimo laasan bi igbati oni kaluku wa loruko tire ti won npe, sugbon APINTANBI ni oruko nla to kari lati ka maa fi pe awon iyawo wa.

 
Ejeki a gbo nkan ti odu mimo OGBEDI so funwa:
Ijakariwo oju ina lo Mona sokun a difa fun APINTANBI Orunmila eyiti nfojojumo nsogun ìyanù won ni ko karaale ebo ni ki o wa se, òdídí oriba, odidi atare kan ati igba ewe ayajo ifa o kabomora o rubo won se sise ifa fun, lehin naa o segun aisan iyanu to nbaja o si di olomo laye o wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare, Orunmila ni bi mo saigbon bi mo saimoran oni semi ko mo wipe òdídí òrìbà lo ndi oriba lenu ni.

 
Nibiti, ifa nsoro nipa obinrin re kan ti oyun nbaje mo lara wipe ki won se aajo fun ki o baa le di olomo laye.
Ifa si tun tesiwaju si ninu odu mimo OKANRASODE lati jeki a mo wipe “APINTANBI” ni obinrin oun(eleyi to tumo si wipe oruko to ye ki awa babalawo maa pe obinrin wa niyen).
Ifa naa ki bayi wipe:
Orunmila ni kutukuti misode
Moni ide werewere lowo awon ologboni
Orunmila ni ki nbi “APINTANBI” leere wipe se o panu?
Oni to bati panu oni apintanbi naa a maa ni sékéséké owó
Orunmila ni kutukutu misode
Moni ide werewere lowo awon ologboni
Oni ki a bi APINTANBI leere wipe se o panu?
Oni to bati panu oni apintanbi naa a maa ni gbinkin inu
Orunmila ni kutukutu misode
Moni ide werewere lowo awon ologboni
Oni ki nbi APINTANBI leere wipe se o panu?
Oni ti o bati panu oni apintanbi naa a maa ni dùrùgbè eyin orun
Orunmila ni sekeseke owo loruko ti a npe owo(ajé)
Gbinkin inu loruko ti a npe omo
Durugbe eyin orun loruko ti a npe olà
Orunmila ni nkan meta ti awon apintanbi toun gbudo maa ni niyen ki won to le maa pewon niyawo oun Orunmila.
Eyin eniyan mi, emase jeki awon alailoye babalariwo yi da ona eko yin ru o, ailopolo ati ainimo toye kooro lo nda won laamu o, otito oro enu Orunmila ni e tigbo yi o.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe aboyun ile yio maa bi were, awon agan yio maa towo ala bosun won yio maa fi pa omo lara, ao rije ao rimun ao rina ao si rilo, idunnu ni ao fi pari ojo oni lase eledumare aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

Faniyi David Osagbami

English Version  :

Continue reading after the page break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo