Home / Àṣà Oòduà / Ẹ ẹ̀ ṣi nọ́ńbà mú l’Ọyọ, gbogbo owó yín tí mo bá ná, ẹ ó rí n tí mo fi se – Seyi Makinde

Ẹ ẹ̀ ṣi nọ́ńbà mú l’Ọyọ, gbogbo owó yín tí mo bá ná, ẹ ó rí n tí mo fi se – Seyi Makinde

Ẹ ẹ̀ ṣi nọ́ńbà mú l’Ọyọ, gbogbo owó yín tí mo bá ná, ẹ ó rí n tí mo fi se…..Seyi Makinde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí Ọlọ́run bá sẹ̀rí ì rẹ,jẹ́ kí èèyàn náà ó sẹ̀rí ì rẹ .
Gomina ìpínlẹ̀ Ọyọ, Onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde tún ti fọwọ́ méjéèjì sọ̀yà fún àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọyọ pé, òun kò ní ná owó wọn ní inakuna. Ó ní gbogbo ohun tí òhun bá fi owó wọn se, ni wọn yóò fi ojú rí.
Gomina Makinde jẹjẹ yii lọjọ Aje lasiko to n se ayẹwo awọn isẹ agbase mẹta nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Ọyọ.


Gomina Makinde lo sabẹwo gareji ọkọ to wa ni Sango, ile iwosan Jericho ati ile igbẹbi tuntun to wa ladugbo Jericho bakan naa, to si koro oju si ipo tawọn dukia ijọba ọhun wa, paapa awọn ilẹ ati ọpọ ohun eelo ti wọn ti pa ti.
Gomina ni asa ti ko dara ni ki wọn maa na owo ilu ninakuna lori awọn isẹ agbase kan, ki wọn si pada wa pa isẹ ọhun ti nigba ti isẹ naa ba de idaji, lai naani owo tuulu ti wọn ti na le lori.

Makinde ni iru asa yii lo wọpọ lasiko ijọba to kogba wọle nipinlẹ Ọyọ, to si tun seleri fawọn eeyan ipinlẹ naa pe ijọba oun yoo ri daju pe wọn fi oju ara wọn ri ohun ti oun ba fi owo ilu se.

Makinde wá pàsẹ fún olùdarí ilée tó ń sàkóso ètò ìrìnà lójú pópó ní ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ọmọwe Akin Fagbemi, láti gbé olú iléeṣẹ́ rẹ̀ lọ sí gárèjì ọkọ̀ àtijọ́ to wà ní Sango, pẹ̀lú ìlérí pé òun yóò pèsè àwọn ohun èlò to yẹ síbẹ̀ fún ìdẹ̀rùn iṣẹ́ wọn.

Iroyinowuro

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo