Home / Àṣà Oòduà / È̩ ń fi ẹ̀wọ̀n run imú ẹ̀yin Olóyè Ìbàdàn mọ́kànlélógún tẹ ń ǹ pera a yín lọ́ba

È̩ ń fi ẹ̀wọ̀n run imú ẹ̀yin Olóyè Ìbàdàn mọ́kànlélógún tẹ ń ǹ pera a yín lọ́ba

Ọrọ̀ kò tíì tán lórí àwọn Olóyè mọ́kànlélógún tí Ilé ẹjọ́ sọ pé kí wọ́n lọ rọọ́kún nílé nílùú Ìbàdàn.

Kọmíṣọ́nnà ètò ìdájọ́ tẹ́lẹ̀rí nípìńlẹ̀ Oyo, Ọ̀gbẹ́ni Michael Lànà ló ṣe ìkìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n yé pe ara wọn ní ọba káàkiri, bí bẹ́ẹ̀kọ́, wọ́n ń fi ẹ̀wọ̀n run imú ni.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Ọ̀gbẹ́ni Lànà fi síta lọ́jọ́ Ajé, ó sọ wí pé bí àwọn Olóyè náà tí ń pe ara wọn, tí wọ́n sì ń gbé ara wọn gẹ̀gẹ̀ bi ọbí lòdì sí àṣẹ ilé ẹjọ́.

”Ìgbésẹ̀ ìjọba àná nípìńlẹ̀ Ọyọ tó fún àwọn Olóyè mọ́kànlélógún láti máa dé adé ìlẹ̀kẹ̀, àti láti máa pe ara wọn ní Ọba lòdì sí òfin,” Ọ̀gbẹ́ni Lànà ló wòye bẹ́ẹ̀

Ó ṣàlàyé síwájú síi pé ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wáyé lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù Kọkànlá ọdún 2019 ti gbé ìgbésẹ̀ ìjọba àná lórí àwọn Olóyè Ìbàdàn sẹ́ẹ̀gbẹ́ kan.

Ọ̀gbẹ́ni Lànà ṣọ pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àwọn kan sì tún ń wọ adé ìlẹ̀kẹ̀ tí wọ́n sì ń pe ara wọn ní Ọba ìlú Ìbàdàn.

Ó ní Ìjọba kò ní bèṣùbẹ̀gbà láti gbé ìgbésẹ̀ lórí bí àwọn Olóyè mọ́kànlélógún náà ṣe ń pe ara wọn ní Ọba káàkiri.

Ọ̀gbẹ́ni Lànà wá ké pe Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ Ọyọ pé kó pàṣẹ fáwọn agbófinró láti fi ọwọ́ òfin mú ẹnikẹ́ni nínú àwọn Olóyè náà tó bá ń pe ara rẹ̀ lọ́ba.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo