Home / Àṣà Oòduà / ÈDÈ YORÙBÁ

ÈDÈ YORÙBÁ

ÈDÈ YORÙBÁ

Èdè Yorùbá ṣe pàtàkì;
Ó ṣe kókó.
Ẹ̀yin ọmọ Oòduà,
Ẹ jẹ́ ká máa rọ́jú s’èdèe wa.
Èdè òǹluko kọ́ l’èdèe Yorùbá.
Èdè tó gba’yì tó gb’ẹ̀yẹ ni.
Àìkọ́mọ l’áhọ́n-ìbílẹ̀,
Ní sábàbí ìwà ọ̀yájú.
Ọmọ yín jí ní kùtùkùtù,
Kò mọ bá a ti ń dọ̀bálẹ̀ kí baba.
Àtikúnlẹ̀ ọmọbìnrin ìwòyí a dìdààmú ńlá.
Ọ̀pọ̀ a lanu gbàù,
Wọn a la’rúkọ m’ágbà lórí.
Háà!
Ó dá mi lójú gbangba,
Èdè àpọ́nlé l’èdèe Yoòbá.
Ọmọ Aládé ló ni ká bọ̀wọ̀ àgbà.
Èdè tí í kọ́ni níwà ni Yorùbá.
Èdè tá a fi í ronú láròjinlẹ̀;
Èdè tó kún mi lójú jọjọ kúkú ní í ṣe.
Gẹ̀ẹ́sì Gẹ̀ẹ́sì șá ni wọ́n fi kó wa lẹ́rú.
Bí Gẹ̀ẹ́sì ‘ò bá ti já gaara lẹ́nu,
Àwọn òpè a ṣe bí tọ̀hún ‘ò nímọ̀.
Bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ tayọ èdè gédégédé.
L’ára ìmọ̀ l’èdèe wà.
Èdè kan ‘ò sì kúkú jù’kan lọ,
Àwa la ‘ò nááníi tiwa.
B’ónígbá bá sì ṣe pe’gbá ẹ̀,
Bẹ́ẹ̀ l’ayé á bá a pè é.
Ọmọ-àlè nìkan ni kì í gb’édè ilé bàbá ẹ̀.
Ó ṣe láraa wa nílẹ̀ yìí.
A gb’òmìnira ìșèjọba,
A ‘à gb’òmìnira èdè.
Èdè Yorùbá ‘ò ní parẹ́.
Àwọn tó gbé e níyì ‘ò ní parun.
Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè ‘ò ní bàjẹ́.
Ẹgbẹ́ Akéwì ẹ kú ișẹ́ takuntakun.
Àbáláyée Nàìjíríà,
Ișẹ́ tó yakin lẹ ń f’ojoojúmọ́ ṣe.
Gbogbo ilé-ișẹ́ rédíò,
Gbogbo ilé-ișẹ́ ìwé-ìròyìn,
Tó ń gbé èdè abínibí lárugẹ,
Iwájú lẹ ó máa lọ.
Gbogbo olólùfẹ́ èdè àtàtà,
Tí í ṣe èdèe Yorùbá,
Ẹ ‘ò ní pàdánù.

Àmín àṣẹ!

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo