Home / Àṣà Oòduà / Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi?

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi?

Eku ise ana o, a si ku popo sinsin odun o emin wa yio se pupo loke erupe ninu alaafia ara o, bi a se njade lo loni eledumare ninu aanu re yio fi iso ati aabo re bowa lowo ibikibi yio wu ko fe sele loni o ase.
Eyin eniyan mi, mofe fi asiko yi dagbere fun yin lori ero ayelujara yi wipe ayo ati idunnu ni ao tun fi pade lodun tuntun to nbo, emin enikookan ninu wa koni pin ki odun to nbo naa o to de o.

 
Sugbon ki nto maa lo, mofe fi akoko yi tun gba eyin eniyan mi nimoran gegebi mo se nse tele, a ri wipe odun 2016 ti lo bayi, nje kini oun ti o gbese lodun yi? Lodun to koja mo gbayin nimoran wipe awon baba nla wa maa nso wipe “ikoko to ba maa je ata idi re a gbona”, moni ki e to Orunmila barami agbonmiregun lo ki e lo beere si ona abayo orire yin lodun tuntun sugbon o semi laanu wipe opolopo lo ka oro naa ti won ko mu lo rara, sugbon odun tuntun miran lo titun wole de yi o, e lo sodo awon babalawo to gboju to mo ifa ati sise re ki e lo beere bi eo se lu aluyo lodun 2017 ki e si se etutu ti won ba so funyin ki e ni igbagbo ninu eledumare ki e si maa gbadura loore koore ki eyin naa le bo lowo inira aye, ki e wo ise ti Oba mi alaurabi yio se ninu igbesi aye yin.

 
E mase joko tetere mo boya mana kan nbo lai gbiyanju ninu aye, iyanju lo maa nmu ki eniyan tete debi ayo re, Yoruba bo; won ni eni to ran ara re lowo lorisa oke ngbe, mofe ki aye yin ni itumo lodun 2017, mofe ki e gbe igbe aye irorun ki e mase bawon paruwo wipe ilu le mo, mofe ki odun 2017 je odun ara meriri ninu igbesi aye yin.
Eyin eniyan mi, e gbiyanju amoran yi ki e wo nkan ti Oba mi onise ara to tobi julo yio se ninu aye yin.
Mo gbaladura laaro yi wipe gbogbo wa ni ao kirawa ku orire lodun tuntun, niwonba ojo die toku ki odun yi pari kosi eni to maa Ku iku ojiji o, odun 2017 yio je odun itusile ati ijeri si agbara eledumare o.
Odigba kan na ti ao tun fi pade lodun to nbo pelu ayo ati idunnu aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version:

Continue after the page break

About Lolade

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo