Home / Àṣà Oòduà / Faleke faake kori nipinle Kogi

Faleke faake kori nipinle Kogi

*Nje ona abayo wa fun un mo?

*Nje igbeyin oro re ko ni di ti Sonroye bayii?

*Kini ipa ti Tinubu ko lori oro yii?

Ogbeni Abiodun Faleke to je igbakeji oludije fun ipo gomina ipinle Kogi to doloogbe, Abubakar Audu, ti ko la ti faramo ibi ti ile ejo to gaju ni ilu Abuja da ejo re si.  Ninu ejo ti Faleke gbe siwaju ile ejo lo ti pe fun idaduro eto idibo eleyii to waye lojo Satide to koja yii nigba to tun fi kun un fun ile ejo wi pe, ki ile ejo naa pase fun INEC lati kede re gege bi gomina tiluu dibo yan.

 

Ejo yii ni onidajo Gabriel Kolawole da nu gege bi ejo ti ko lese nile rara. Leyin eto idajo to waye yii ni ogbeni Faleke ti fi da awon oniroyin loju wi pe ile ejo kotemilorun ni o pada tun ejo naa da gege bo ti ye. Faleke ti ro awon ololufe re lati lo mu okan bale, ki won si yago fun iwa jagidijagan to le di alaafia ilu lowo.

Okan ninu awon agba oloselu kan lati inu egbe oselu APC, eni to gba lati ba akoroyin wa soro lai se afihan oruko re, so wi pe yoo soro fun APC ipinle Kogi lati fa Faleke sile gege bi eni ti o ropo Audu to doloogbe. Ninu oro re, o ni yoo soro fun Faleke lakore nibi ti o funrugbin si.

Ninu afikun re, o ni awon oloye egbe APC ti ipinle naa tun gba wi pe oselu Kogi ko ti i fi gbogbo ara ye Faleke eni ti pupo iriri ogbon oselu re je ti ipinle Eko. Ogbeni Faleke ti fi igba kan je alaga ijoba ibile Ojodu to wa ni ipinle Eko fun igba meji. Bakan naa lo ti soju awon eniyan agbegbe Ikeja to wa nipinle Eko kan naa nile igbimo asoju-sofin Abuja.

“Bi o tile je wi pe omo bibi ipinle Kogi to wa lati ijoba ibile Ijumu ni Faleke, sibesibe, eni ti ko se nidi pepe ko le je nidi pepe,” agba oloye egbe APC fi kun bee. Lara awon awuyewuye to tun gbale ni ero awon kan wi pe ti Faleke ba di gomina, Bola Tinubu ni yoo tun maa dari ipinle Kogi.

Ninu oro ti akowe ipolongo fun egbe PDP, Olisa Metuh fi sita, o ni nipa wi pe oludije labe egbe oselu APC padanu emi re ni akoko idibo naa fidi re mule wi pe egbe PDP ti jawe olubori. O si fesun kan ajo INEC nipa liledi-apo-po pelu PDP lati doju oro naa bole.

“Ka maa se pasipaaro oludije laaarin meji eto idibo ki i se ohun ti a ri ka ninu iwe ofin ile Naijiria rara. Iku oludije APC fi da wa loju wi pe won ti padanu idije fun ipo gomina ipinle Kogi,” Metuh fi kun oro re bee.

Ogbeni Metuh ko sai pe fun ikowefiposile minisita fun eto idajo, Abubakar Malami, pelu bo se n se atileyin fun egbe APC eleyii to gba wi pe o tako iwe ofin ile wa.

Lori oro yii kan naa, Gomina Ayodele Fayose ti ipinle Ekiti ti naka aleebu si Aare Buhari gege bi enikan to n lo minisita fun eto idajo, Malami, lati dori oro kodo mo ajo INEC lowo. Oro yii ni Fayose so lati enu oludamoran re nipa oro-to-n-lo ati iroyin ayelujara, Ogbeni Lere Olayinka.

Oro enu Idris Wada naa ko sai yato si ohun ti awon alatileyin re lati inu egbe PDP ti n wi nipa wi pe ona eru ni ajo INEC gbe eto idibo naa gba. Manaja fun eto ibanisoro gomina, Ogbeni Phrank Shaibu naa si fi ye awon oniroyin wi pe ile ejo ni yoo pada yanju oro naa nitori wi pe gomina Idris Wada loye ki won kede gege bi gomina tilu dibo yan leyin iku alatako re.

Pelu bi nnkan se wa ri yii, ohun ti o je igbeyin oro Faleke ko ti ye enikeni. Se Faleke o faramo ipo igbakeji gomina abi yoo tepelemo ifisun re nile ejo lati gba ipo gomina pada? Opolopo awon eniyan ni won tile n reti akitiyan oloye Bola Tinubu lati dasi oro naa sugbon ti ohunkohun ko ti odo agba oloselu naa jade.

Awon kan tile n so ni awon agbegbe kan wi pe oseese ko je Tinubu lo n ki Faleke laya lati gbe ejo naa lo si ile ejo kotemilorun. Sugbon sa, ti oloye Tinubu ba pada soro lojutaye, se ni o da Faleke lekun ni, ti o si pase fun-un lati gba ipo igbakeji gomina tabi yoo naka abuku si awon agba omo egbe ti won tako Faleke nipinle Kogi?

 

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo