Home / Àṣà Oòduà / Ijamba oko niluu Eko lojo odun keresimesi

Ijamba oko niluu Eko lojo odun keresimesi

Ti e ba muti, e ma wako; ti e ba wako, e ma muti. Okunrin kan lo koja lo sorun lojo odun keresimesi to koja yii ni akoko ti gbogbo eniyan n yo ayo iwasaye Jesu olugbala araye. Ijamba oko yii lo waye ni oju ona Mobolaji Bank Anthony to wa ni Ikeja ni ipinle Eko.

Gege bi awon eso oju-ona FRSC se so, won ni ere asapajude ni okunrin naa n saa bo lai se wi pe enikeni n le ko to di wi pe oko re takiti laimoye igba. Oju-ese naa ni emi jade lara okunrin naa, eni ti enikeni ko ti mo ohunkohun nipa re titi di akoko ti a n fi ko iroyin yii.

Sugbon iwadii inu awon eso oju-ona fi ye wa wi pe, ogidi oti amupara ni okunrin naa mu yo saaju ko to se agbako iku ojiji naa. Won ti gbe oku okunrin naa lo si ile igboku si nigba ti won si n se iwadii nipa awon ebi re.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo