Home / Àṣà Oòduà / Ìjọ Kátólíkì Bẹ̀rẹ̀ Ìwáàdì Lẹ̀yìn Tí Àwọn Sisitá Méjì Lóyún Ójijì

Ìjọ Kátólíkì Bẹ̀rẹ̀ Ìwáàdì Lẹ̀yìn Tí Àwọn Sisitá Méjì Lóyún Ójijì

Ìjọ Kátólíkì bẹ̀rẹ̀ ìwáàdì lẹ̀yìn tí àwọn sisitá méjì lóyún ójijì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Eemọ̀ lukutu pẹ́bẹ́,kò síbi tí ìṣe ò sí. Ayé dojú kejì, wọ́n ń bámí ẹran níhòòdí ọmọ èèyàn. Ìjọ Kátólíìkì ti ń ṣe ìwádìí bí àwọn sista méjì kan ṣe lóyún lẹ́yìn tí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nílẹ̀ Áfírìkà. Àwọn obìnrin méjéèjì náà tó jẹ́ olùgbé ìlú Sicily, lórílẹ̀-èdè Italy, tí wọ́n kìí ṣe ọmọ ìjọ kan náà, ni wọ́n ń dúró de ọjọ́ ìkúnlẹ̀ báyìí.


Ọ̀kan lára àwọn obìnrin ọ̀hún, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ sí ilé ìwòsàn nítorí inú rírun, kí Dókítà tó fún- un ní ìròyìn pé oyún ti dúró sára rẹ̀.
Ìjọ Kátólíìkì tó wà ní ìlú Rome sọ fún àwọn akọ̀rọ̀yìn pé, ìgbà tí àwọn obìnrin náà rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ adúláwọ̀ ni wọ́n ní ìbálòpọ̀.
Ìjọ ọ̀hún tẹ̀síwájú pé àwọn obìnrin náà rú òfin tó jẹ mọ́ Ẹ̀sìn àti iṣẹ́ tí wọ́n gbà, bẹ́ẹ̀ ni ìwádì ti bẹ̀rẹ̀ lori bí wọ́n ṣe di aláboyún òjijì.


Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni olórí ìjọ Kátólíìkì lágbàáláayé , Pope Francis ti sọ ṣaájú pé, àwọn Bísọ́ọ̀bù kan má ń fi ipá bá àwọn sista ní àjọṣepọ̀, kódà ó ní wọ́n ń fi àwọn mìíràn lára wọn ṣe ẹrú ìbálòpọ̀. Popu ṣàlàyé pé, bí àwọn Bísọ́ọ̀bù yìí ṣe ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin náà jẹ́ ìsòro ńlá nínú Ìjọ Kátólíìkì.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo