Home / Àṣà Oòduà / Ọmùtí Gbàgbé Ìṣẹ́ (Ìrònú Ọlọtí)

Ọmùtí Gbàgbé Ìṣẹ́ (Ìrònú Ọlọtí)

Ilé ọlọ́ti ni ilé ìtura, ibẹ̀ ni àwọn ọ̀rẹ́ ti npàdé fàájì
Ibẹ̀ náà ni àwọn èké, àti ọ̀dàlẹ̀ tin pàdé ara wọn
Ti ọti bá wọra tán, ara a sì rọ̀ wọ́n pẹ̀sẹ̀,
Ìgbéraga á wá wọ̀ wọ́n lẹ́wù
ọ̀rọ̀ á wá di dánmi wò, ngó ṣe bí mo ṣe tó
Bi mí́ léèrè nsèké, ó wá di mo sọọ́ tán, àsírí tú
Ìjà ọ̀dàlẹ̀ kò sì tán bọ̀rọ̀,
ngó gbẹ̀san, ọ̀dàlẹ̀ di méjì
Tani kí a báwí? ṣé ọtí ni?
Tàbí ọlọ́bọ̀bọ̀tiribọ̀?

 

omuti

Adeboye Adegbenro

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo