Home / Àṣà Oòduà / Odo Iwoyi – E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo

Odo Iwoyi – E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo

 

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Odo Iwoyi wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.

Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e n se lori eto yi, Ile tiyin na ko ni daru lase Olodumare. Beeni mo ki gbogbo eyin ojogbon ti e n da seto yi, Eledua yoo da soro aye tiwa pelu lase Olodumare.

Olootu e jowo oro kan nii ru mi loju ti mo si nilo amoran awon ojogbon lori re, Arabinrin kan ni emi ati re jo n se wole-wode ti o si je gege bi afesona mi, mo ni ife arabinrin yi pupo ti mo si mo wi pe oun pelu ni ife mi.

Ipa ti mo ko ninu oro arabinrin yi ko kere ni akoko ti o wa ni ile eko poli, o fere je wi pe emi ni mo ran arabinrin yi ni ile eko ni, kii kuku se wi pe awon obi re ko fe se sugbon o po lowo won ni, leyin ti arabinrin yi pari eko poli ti ko si agbara lati tesiwaju ni a jo gbero wi pe boya ki o lo ko ise owo tori ise owo ko se f’owo ro seyin laye ode oni, paapa julo fun obinrin.

Beeni arabinrin yi bere ise owo ti mo si tun bere ojuse mi biti ti ateyin wa. Sugbon iyalenu ni o je fun mi ni akoko kan ti awon ore mi n pe mi lotun losi ti won si n se kilokilo fun mi wi pe, ipa ti mo n ko lori oro aye arabinrin yi ti po ju niwon igba ti kii se wi pe a ti fe ara wa sile, nse ni o ye ki n maa rora se tori obinrin buru pupo.

Eyi ti o wa je pabanbari oro yi ni bi maami ati baami se pe mi ni ojo aiku ti o koja lo yi ti baami si tenu bo oro wi pe:-

“Akin mo mo wi pe ologbon omo ni o, sugbon bi o ti wu ki o ri o si wa labe itoni awa obi re, woo oro iwo ati afesona re ni a fe ba o so, ti o ba je laye igba tiwa ni, maa wi pe ko sohun to buru ninu iwa ti o n hu yi sugbon nibi ti aye de loni oro okunrin ati obinrin gba ogbon o, Eledua o ni je ki a sise fun elomiran je o, ohun ti mo n so gan ni wi pe ipa ti o n ko lori oro arabinrin yi ti po ju laiki i se wi pe e ti fe ara yin gege bii loko-laya, woo kii se wi pe o buru lati ran afesona re lowo sugbon iwontun iwonsi ni gbogbo nkan, pelu gbogbo ipa ti o ko lori re ni ile eko, mo gbo wi pe iwo ni o tun n gbe oro ikose re, hmmm rora o, se o mo wi pe eniyan ni eniyan yoo maa je? Opo awon ti a n gbo lotun losi wi pe won pa ara won nitori obinrin, kii se ife ni o fa fun opo won o, bikose arokan awon ohun ti won ti padanu, Eledua o ni fi eyi se ipin wa o, abo oro ni a n so fun Omoluabi o”

Bi baami se danu duro ni maami pelu mi kanle ti won si wi pe “Hmmm e seun jare baale mi Eledua yoo kuku je ki a jere won, woo Akin se o mo wi pe ile aye yi ni o ba emi ati baba re, a o si le ti o sinu ina, kii se wi pe a lodi si bi o se n ran afesona re lowo o sugbon ki o kiyesara tori eyin omo aye ode oni, e o se fokan tan o, Eledua o ni je ki a se lasan o, a o si ni sise fun elomiran je lase Olodumare”

Hmmm bi maami ti danu duro ni mo dobale ti mo si ki awon mejeeji fun amoran iyebiye yi. Leyin ti mo kuro lodo awon obi mi, mo wa joko mo nronu oro yi, nse ni mo n bi ara mi wi pe ki ni o buru gan lori ipa ti mo n ko lori oro afesona mi yi, sebi ojo ola idile mi ni mo n tun se? Sebi awon agba na ni won wi pe ki a fi owo we owo ni owo fi n mo?

Oro na wa ru mi loju, nse ni o ngbe mi ninu lati bi awon obi mi ni ibeere yi sugbon n ko fe maa gbo won lenu, eyin ojogbon eto Odo iwoyi e dakun ki ni o buru ninu ki okunrin maa ran afesona lowo gan? E jowo mo nilo amoran yin pelu alaye ti yoo ye mi yeke ati awon Odo egbe mi ti a wa ninu ipo yi, oro mi ko ju bayi lo, ile gbogbo wa ko ni daru lase Ollodumare ”

Hmmmm oro ree o, iriri kuku sagba ogbon ni awon Oloye eniyan wi, eyi baami ati maami nile, eyin ojogbon ati oloye eniyan, e jowo ojo wo ni eyin fi wo oro ile yi gan? Se looto ni oro awon baba arakunrin yi abi boo? e jowo e ba wa da si o…

 

Abel Simeon Oluwafemi 

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo