Home / Àṣà Oòduà / Olise dubule aisan leyin ti Emmanuel Emenike dagbere fun egbe Super Eagles

Olise dubule aisan leyin ti Emmanuel Emenike dagbere fun egbe Super Eagles

Akoni-moogba egbe agbaboolu Naijiria, Sunday Oliseh ni won ti gbe digbadigba lo si ilu Belgium bayii fun itoju. Ajo ti n dari ere boolu Naijiria, The Nigeria Football Federation lo so eleyii di mimo loju opo won [@thenff] eleyii to kale sori Twitter.

Ojobo ose to koja yii ni won fi baalu funfun nla gbe Oliseh jade niluu Potakootu lo siluu Belgium nibi won ti n toju re.

Lojo Oru ose to koja ni Emmanuel
Emenike, okan lara awon egbe agbaboolu Super Eagles kede lori ero ayelujara wi pe akitiyan oun ti pari pelu egbe agbaboolu naa.

Eleyii ti Oliseh so wi pe o je iyalenu ati ohun to soro lati gbagbo. E maa gbagbe pe, Vincent Enyeama naa kede ifeyinti re laipe yii ninu egbe Super Eagles.

Titi ti a fi se akojopo iroyin yii, a ko le so pato orisii aisan to n se Oliseh, eni ti itoju re si n tesiwaju niluu Belgium.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

O se o Eledua ! Alaafia ti n pada sara Oliseh

Akonimoogba egbe agbaboolu Super Eagles, Sunday Oliseh, si wa ni ile iwosan niluu Belgium nibi to ti n gba itoju lowo. Iroyin tuntun to te Olayemi Oniroyin lowo lati enu awon dokita isegun oyinbo ti n toju re fi ye wa wi pe alaafia ti n pada si ara Oliseh, eni to je okan lara egbe agbaboolu Julius Berger tilu Eko lodun 1990. Ti e ko ba gbagbe, ojo kejilelogun osu kewaa odun yii (22/10/15) ni won gbe Oliseh digbadigba ...