Home / Àṣà Oòduà / Oro Nipa Ose Olubadan: Idi Ti Egúngún Kankan Ko Se Nde Oja Oba Ibadan Di Oni Oloni Mo

Oro Nipa Ose Olubadan: Idi Ti Egúngún Kankan Ko Se Nde Oja Oba Ibadan Di Oni Oloni Mo

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isimi opin ose oni, adura wa yio je itewogba lodo eledumare o Ase.
Laaro yi mofe se idanileko nipa idi to fi je wipe egungun kankan ko se nde oja oba ibadan mo di oni oloni, se e mo gegebi mo se maa nso tele wipe ifa nikan lo le tan imole si ohunkohun nipa itan isedale awa Omo adulawo julo, opolopo itan lo wa tabi àló nigba miran ti Yoruba maa nso to je wipe inu odu ifa ni won ti jade, mo nfe ka mo wipe ko ki nse eewo ni ki egungun ma sere de oja oba nilu ibadan sugbon o nibi to ti fa ko toso.

Olubadan
Idi niyi ti mo fi sope ifa ni imole fun gbogbo nkan kinkan ti eledumare da.  E jeki a gbo nkan ti odu ifa mimo ose meji/ose olubadan so nipa idi ti egungun ki se fi nde oja oba ibadan mo di oni oloni.
Ifa naa ki bayi wipe:
Iké ni iké sóko
Mòbà ni mòbà toro
Lánùújù ni baba eku
Lánùújù ni baba eja
Lánùújù ni baba eye
Lánùújù ni baba eran
Lánùújù ni baba eniyan
Bi a ba de ìlú
Ile Oluwo ni a ndesi
Odede ojugbona ni a nya
Aidodo ojugbona ko jeki a dele oluwo
A difa fun òpó lojo ti nlo ree lawon lágàn lode ibadan, ara ibadan ni airomobi nyo lenu lopolopo, okiki òpó lo kan nipa ise ribiribi to se lode oyo oun ni olubadan gbo lo ba ranse sii wipe ki o wa ba oun naa se ìlú oun ki won le di eleniyan pupo ninu ìlú won, nigbati òpó si de aafin olubadan o dafa fun won o si ni ki won rubo nitori ki won baa le di olopo eniyan ninu ìlú won, ki ìlú ma baa si ti mo olubadan lori, obi meji, ewure meji, igba igbin, ikoko ori ati igba ewe ayajo ifa, olubadan si kabomora lesekese o si rubo, òpó fi awon igbin yen nse aseje ifa fun awon agan ti won nwoju eledumare awon eleyi ti kori aseje je o lo ikarahun igbin wonyen pelu ewe ayajo ifa oni ki won o maa fi fo ori mun, ko pe ko jina won ri wipe obinrin olubadan loyun nigbati o maa pe osu kesan o si bi omobinrin eyiti won so oruko re ni (NKAN), bee naa sini adura awon toku bere sini ngba ti gbogbo won si nbimo, ko pe seni NKAN omobinrin olubadan ndagba bi eni nroo, seni olubadan wa fun òpó wipe ki o fi Omo oun se iyawo re fun fifi emin imoore han si, inu gbogbo ara ìlú ibadan si dun si òpó lopolopo.
Nigbati o di Ojo kan, seni òpó nlo soja oba lojo ose ifa to fe lo ra obi ti yio fi se Oke iponri re, awon ara ibadan naa si ti gbe egungun lati lo fi se ayesi òpó latari oore nlanla to se funwon, bi won se maa wo iwaju seni won nwo òpó niwaju bi won se na ika si niyen ti won nsope òpó re, òpó re, òpó re bi won se nsa lo sodo òpó niyen laimo wipe òpó ko sawo egungun, bi òpó seri ara ibadan ti won ndaruko re ti won nawo si ti won si nsa bo lodo re seni òpó ba gbanaya to nsalo sodo Oke ibadan, nigbati o maa de odo Oke ibadan òpó wa ni ki Oke ibadan gbahun o oun ko mo nkan ti oun se fun ara ibadan ti won fi nle oun o, ah! Se eleyi ni won yio fi san oore toun se funwon?

 

Ni Oke ibadan wa ranse lo pe olubadan ati awon ara ìlú lati wa salaye nipa Ohun ti òpó se to fi je wipe ibi ni won fe fi san oore fun-un, nigbati won de odo Oke ibadan, olubadan si salaye wipe awon ko ni aburu kankan ninu lati se fun òpó o, awon fe wa fi egungun sere fun ni nipa imoriri oore nla to se funwon lode ibadan, olubadan ni koda Omo ti won koko bi òpó naa loun fifun ko fi se aya re, bi Oke ibadan se wa sofun òpó niyen wipe awon ara ibadan feran re wipe won ko ro nibi o Oke ibadan wa ni ki òpó o maa lo sile re sugbon iberu si wa lara òpó ni òpó bani ti awon ara ibadan ko ba se ileri fohun wipe egungun kankan koni wa sibiti oun ti nra awon eroja etutu oun koni pada sile, lesekese naa ni awon ara ibadan se ileri fun òpó wipe Kosi egungun kankan ti yio tun debi ti o ti nra awon eroja etutu ifa re layelaye mo, bi òpó se pada sile re to ngbe leyin Oke ibadan niyen o, awon ara ibadan wa njo won nyo won nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare won ni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu Omo jebutu Omo ni a nbawo less obarisa.

 
Idi niyi ti egungun kankan ko se nde oja oba ibadan mo di oni oloni oo, ikarahun igbin ti won si fi fo ori mun fun won nigbayen ni won se nkiwon wipe; ibadan Omo afikarahun foriimun.  Eyin eniyan mi, mo se ni iwure Laaro yi wipe Ijade wa koni bi Omo araye ninu, ìyà eniyan Kosi ni jewa gbogbo adawole wa yio yori si rere oo aaaaase.
Emi gigun fun gbogbo eyin ololufe mi ati Omo ibadan gbogbo oo.
ABORU ABOYE OOO.

 

 

ENGLISH VERSION
Continue After the Page Break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Olubadan

Awon omo Alade yari: Yoruba fe gba’ra re lowo ajeji Fulani to n tele basubasu

Akeredolu yari kanle. Olubadan ni ki Seriki Sasa fi owo sibi owo o gbe… . Akeredolu yari kanle. Olubadan ni ki Seriki Sasa fi owo sibi owo o gbe. Gani Adams n yona lenu lori laasigbo Wakili. Sunday Igboho si gegun kale Igbaniloju naa ti n lo, ojo pe die, sugbon bayii, o jo pe ile Yoruba ti setan ati gba ara re kale lowo ajeji godogba to n te’le basubasu.Awon atilaawi yii gan-an ni awon Fulani, paapaa awon darandaran, ...