Home / Àṣà Oòduà / Oro Sunuku – Ore Mi, Iran Kefa .

Oro Sunuku – Ore Mi, Iran Kefa .

.( Ni gbongan adulawo ni Yunifasiti Afonja, awon eniyan n wole leni tere, eji tere. Won n gba tikeeti, won si n wole jokoo. Awon ti o fe safihan sinima naa n gunke, won nso. Won nfa waya, won gbaradi. Ori ife kan rore nlo labele lori ero amohundungbemu ti o wa ni gbongan naa. Femi ati Sola naa wole. Kerekere gbongan naa kun. Won si ni ki awon to ku duro di aago mejo, se ti aago mefa ni won koko se, leye’o’soka ere bere. Itan okunrin akuse ka ti o n wa oko takisi sugbon ti ofa ife re wole si okan odomobinrin omo olowo kan ni. Bi ere yii ti nlo lowo ni awon to mura won wa nlo mo ara won, won soro kelekele seti ara won, bee ni won n rerin lu ara won, ka ma paro, awon eniyan n gbadun ere naa. Femi n poungbe lati se eyi pelu Sola sugbon o nko ara re ni ijanu. Igba to ya. Ere pari, won fori le ile ouje. Ile ounje ti won lo ki i selero repete. Ina buluu resuresu ni won fan sibe. Aga meji’meji lo kiju sira won ni won to si idi tabili kookan. Awon tabili naa si jinna sira won diedie. Femi ati Sola wole, won fun won lounje, ( Won si jeun)
.Femi:. Bawo lo se ri sinima yen si?
.Sola:. O dungan, mo gbadun e.
.Femi:. Ki lo de na ti awon olowo ki i fe omo awon fe talaka?
.Sola:. Ko ye won ni pe owo ko ni gbogbo nnkan. Mo gbagbo pe ife lo se pataki ju. Ti ife ba ti wa, abuse buse.
.Femi:. O ro bee?
.Sola:. Mo mo bee ni. Ati pe eni ti ko lowo lonii. O le ni lola. Mo si gbagbo pe ti tokotaya ba fowosowopo pelu ife, laisi etan, ojo ola won a dara.
.Femi:. Ooto ni. ( Won ti pari ounje, awon osise ibe ti wa ko awo lo. Won n mu waini)
.Femi:. Sola.
.Sola:. Yes.
.Femi:.( O tun idi se lori aga) Mo fe so die fun e nipa mi. Gege bi o se so, mo ti niyawo ri, ( Sola fe gbe ife oti senu tele, bi o ti gbe eyi, o gbe ife oti kale, o fi igunpa le ori tabili, o ki awon ika owo re mejeeji bora won, o gbe agbon le e, o fojuro, o si n wo eyin oju Femi gan, o teju mo). Titilayomi ( O dake die, o tiiri) A feran ara wa bi emi. Odun marun seyin ni a se igbeyawo, aye gbo, orun si mo. O loyun bi gbogbo obinrin se n loyun, a si n reti atigbomojo. Ojo naa re bi ano. Mo wa nibi ise ni Titilayomi pe mi pe oun damira. Mo sare dele, a gbera, o dile iwosan. Loro kan sa, iku o je romo, ko je n ri Titilayomi mo.( Omi oju ti le roro si oju Sola, bi o se seju pe bayii, pere lomi naa dajade loju re)
.Femi:. Rara o. Mi o fe ba e ninu je. Mo kan fe fi e lokan bale pe ki i se pe mo niyan nile, mo fe maa doka lamuu ni.
.Sola:. O ma se o. Odun merin seyin, ki lo wae ti e ko gbiyanju ati fe elomiran? Be esin ba da ni, a a tun gun ni.
.Femi:. Ibi ti mo nlo gan loti saaju mi de yen. Mo ti gbiyanju lati tun gun bi eemeloo kan sugbon se lo dabi eni pe awon esin asiko yii, koriko ti won ma je pere ni won mo, ki i se ife eni ti o fe gun won. Mo si tilekun okan mi pa nitori mi o fe wahala Obinrin. Titilayomi ti ba mi je, o faye ro mi lorun pupo.
.Sola:. E ba ma de se bee o. Olorun aa si gbe obinrin rere pade yin. Mo …
.Femi:. Bee ni. Akinwumi isola ninu O LE KU ni ( igba tilekun mori, o loun o nii dojo lohun. Ojo akoro lo sese ro, igbin tun sile re mori. O n lanna iwo kiri inu omi….)
.Sola:. A, eyin naa tie maa n kawe Yoruba?
.Femi:. Mo ti tilekun okan mi tele, afigba ti mo ri e. Ki n to mo ohun to n sele, mo ti si i sile gbarabada.
.Sola:. A! Emi? ( O fowo soya.)
.Femi:. Bee ni. Laye ode oni, n ko mo pe a si leri odomobinrin ti ori re pe, ti o si fara bale, afigba ti mo ri e. Joo Sola, o o de fe mi.
.Sola:. ( O ya a lenu) Fife bawo, Misita Johnson?
.Femi:. Se o o feran mi ni abi mi o si ni sawawu awon ti o le fe?
……………Won daso bo itage……………..

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo