Home / Àṣà Oòduà / Oro Sunku: Ore Mi, Iran Kerin

Oro Sunku: Ore Mi, Iran Kerin

(Ni nnkan bi aago meje irole ni ibugbe awon obinrin ni ogba Yunifasiti, ero po nibe lokunrin lobinrin. Awon kan n wole, awon kan n jade. Awon okunrin miiran wa ninu oko ayokele pelu awon omoge, won n soro. Awon miiran tile n diro sibi to sokunkun, won nlo mo ara won. Aago merin ni awon okunrin ni afani lati wo ibugbe awon obinrun. Won a fi oruko sile lodo awon asobode ti o wa nibe ki won to wole, won si gbodo jade ni aago mewaa leyin ti won ba ti kowo bowe leekeji. Nipa bayii, afi bi oja ale ni iwaju ibe ma nri lowo irole. Femi loki Sola gege bi ileri re. O wo sokoto pelu ewu saati penpen kan, o si wo salubata olowo pooku kan si. O kan ilekun yara ti Sola fun ni nonba re.)
.

Kunbi:. Yes. Wole ilekun un wa ni sisi.
.Femi:. ( O wole) E ku irole o.
.Kunbi:. ( O woo latoke de ile) Ehen , ta lo n beere?
.Femi:. Sola ni, abi ibi ko ni yara e? ( O wo oju Kunbi dada) Haa, sebi eyin ni mori pelu re ni ose to koja?
.Kunbi:. Sola o si nile ( Gbogbo bi o se n da Femi lohun, oju re o fani mora rara)
.Femi:. Se mo le jokoo de e?
.Kunbi:. Ti owo re ba dile to bee, amo emi n jade lo. ( Gbogbo iwosi yii ye Femi sugbon ko ja a kunra. Eni a n ba naja la a wo, a ki i reti gbo ariwo oja)
.Femi:. E bami ji se fun pe Femi wa. Mo ti pe aago re sugbon won ni o pa a. Ma a tun pe e, o dabo. ( Kunbi ko dahun. Ki Sola tode lati idanileko Kunbi ti jade, oru loto wole, Sola si ti sun. Lojo keji, awon mejeeji n soro ni yara won)
.Sola:. Kare, agbefo baba agberin, ibi gbogbo loju ojo nka! Ibo le tun ri gbalo lanaa o?
.Kunbi:. Iwo lomo. Won fi e so mi ni? Abi gbogbo eeyan loro pe a a joye bojumolemo bii tire.
.Sola:. A to e e ti. Adiye to su ti koto, ara re lowa.
.Kunbi:. Awon booda onisalubata kan ma wa e wa lanaaan.
.Sola:. Ki loruko re, ki lo ni oun wa?
.Kunbi:. Mo ma tie ti gbagbe oruko to da. Sola, mo ti ma n so fun e, so iru okunrin ti o na ba jade. Se eyi ti o fi ewu penpe kebi soke yen lo kan? O o tie ni class rara. O kan ri rasirasi kan sa, boya ni iran re gbooorun owo ri.
.Sola:. Ta lonitohun, abi ko loruko ni?
.Kunbi:. Ani mo ti gbagbe se. O so orukore re o, mi o fokan si ni. Bobo ti o beere ona gbongan ere idaraya lowo wa lose koja yen ni
.Sola:. Haa, Femi niyen.
,Kunbi:. Loto nii ( That’s right) Oruko to da niyen. Wa o, ore, se jo ti e gba jogirafi ese de gbongan ere idaraya le tun wa juwe yara fun ara yin?
.Sola:. Iwo lo mo. Ko o de maa wo o, ki i se ohun ti o ro rara. Bobo yen wa jentuu gan ni. Ki i so nigiragira rara.
.Kunbi:. Sola, aanu e semi, se jentuu la fe je niabi ko lowo lo wo? Bi o tile n se giragira ani ki bondu ti wa lapo e.
.Sola:. Ki lo tile maa n se e pelu owo na? Ka ni omo talaka ni a a pe o loju’o’ rola ri. O ti feran owo ju.
.Kunbi:. O o mo pe owo ni idahun si ohun gbogbo. Owo ni yoo mu awon ti o le bi e pe e ni Moomi. Iwo naa a wa nibi giga pelu awon eyan jankanjankon, owo lo nje bee. Inu owo la bi mi si, oro la fi wo mi dagba. Laelae faabada, n ko le ba talaka se.
.Sola:. Eru e de n ba mi. Kunbi. Ki lo de ti o wa n ba emi sore? Emi ki i saa somo olowo.
.Kunbi:. Bii ti bee yen ko, ore mi niwo. A ni mi o le fe talaka gege bi oko ( o taka danu kuro lori) Eledua ma jee.
.Sola:. Ti eniyan ko ba lowo lonii, ko tun mo si pe ko le ni lola. Ti obinrin ba fe eni ti ko lowo lonii, o le di lola ki Eleduamare ko idi owo si ke.
.Kunbi:. Tie niyen. Ni temi o. Ko si owo, ko si ife, kojubelo.
.Sola:. Iwo lo mo. Eledua ma jee ki o ko sowo alawin. Owo ko nife, aso nla si ko leeyan nla.
.Kunbi:. Ani kini ni bobo yen wa se nibi se?
.Sola:. O wa ki mi ni.
.Kunbi:. Ha! Se ki se pe o fe fe e sa? Bi mo se n wo bobo yen, ko le ni kobo lapo.
.Sola:. Hun, Eledua maa je ki owo ba tie je. Eni eleni o ma soro fife o. Oju o sona funwo ni abo o ri pe o ti niyawo ni? Gbogbo eniyan lo ro pe o n se lagbalangba kiri?
.Kunbi:. Langbalangba yen gan ni iyo ibe, ko ye e ni.
.Sola:. Ti ko ba ti niyawo, ti iwa re ba si temi lorun, ibaa talaka ju ekute soosi, ma a fe e.
.Kunbi:.( O n korin) Olowo mo balo, mi o bolosi tan, Olowo mo balo, mi o bolosi tan. Talaka alailero, abaratarutaru olowo mo balo, n o bolosi tan. ( Bi o ti n korin ni o kun atike ti o si n yera wo ninu diigi bi agbebo adiye. Sola saa n wo o. O se tan, o dagbere, o si jade lo. Sola si wa ni yara, o n kawe ni enikan kanlekun)
.Sola:. E wole o
.Femi:. E kaale nibi o
.Sola:. Misita Johnson, e kaale. E wole, e jokoo ( o nawo sori aga)
.Femi:. O se pupo. ( O jokoo)
…………….. Won daso bo itage……………

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo