Home / Aarin Buzi / Se Ruggedman ba iyawo 9ice sun looto?

Se Ruggedman ba iyawo 9ice sun looto?

Se Ruggedman ba iyawo 9ice sun looto?

*Adigun Alapomeji ti pada soro
*Asiri ikoko ti de gbangba
Olayemi Olatilewa

9ice ati Toni
Alexander Abolore Ajifolajifaola eni ti gbogbo eniyan mo si 9ice ti ni oun ko ni darijin ore oun atijo, Michael Stephens ti opolopo mo si Ruggedman. Laaarin awon igba kan seyin ni awuyeye kan n lo nigboro wi pe Ruggedman ba iyawo 9ice, Toni Payne lajosepo.

Awuyewuye yii lo jeyo latari orin kan ti 9ice gbe jade ni akoko naa to pe ni ‘Once Bitten’.

Ninu orin yii ni 9ice ti n so wi pe oun ka ore oun timotimo pelu ololufe oun nibi won ti jo n ‘jegbadun’ ara won. Kete ti orin yii si jade ni 9ice ko iyawo re sile latari esun asemase.

9ice o daruko enikeni ninu orin re sugbon opolopo awon eniyan gba wi pe Ruggedman lo n bawi.

Ohun to tun bo mu oro naa disu ata yan-anyan ni bi 9ice se ko lati tanna imole si oro naa boya Ruggedman lo n soro ba ninu orin re abi elomii.

Awon onwoye gba wi pe, oun to mu 9ice ko jale lati so pato eni to n bawi ninu orin re ko ju bi awuyewuye to ro mo orin naa se n mu orin naa lokiki sii eleyii to n ja sowo tabua fun 9ice ni awon akoko ta n soro re yii. Sebi won ni maalu to suke, ere lo ja si fun alapata.

Ruggedman
Isele naa bi Ruggedman ninu latari ojuti ati iwosi nla to de ba a latari bi 9ice se taku lati tanna imole si rugudu naa. Ruggedman korin pada bu ore re. Oro di fopomoyo, ikoko imule ore si pada fonka yangayanga bi eyin ti won so lu apata.

Leyin igba pipe seyin ti isele yii ti sele, lenu loolo yii ni 9ice so lori telifisan wi pe oun o le darijin Ruggedman laelae ayafi to ba wa tuba.
“Mi o le darijin Ruggedman ayafi to ba wa toro idarijin lowo mi. Nitori oro ti ko kan an lo n da si. Ruggedman o ba iyawo mi sun, oun si ko ni mo n soro ba ninu orin mi”. – 9ice

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*