Home / Aarin Buzi / Won ti gbe oye Dokita fun Oba Lamidi Adeyemi III

Won ti gbe oye Dokita fun Oba Lamidi Adeyemi III

Leyin ayeye ojo ibi odun metadinlogorin (77) Oba Lamidi Olayiwola Atanda Adeyemi III to waye laipe yii, awon ojongbon tun ti pawopo fi oye Dokita da Alaafin Oyo lola.

Ayeye yii lo waye l’Ojoru to koja yii nibi won ti n se ikojade awon omo akekoo gboye ile iwe Ifafiti Afe Babalola to kale si Ado-Ekiti. Iru ayeye yii ni yoo je eleeketa iru e ti o waye lati igba ti won ti fi ile iwe giga naa lole lodun 2009.

Lara awon eniyan ti won da lola lojo naa ni olori ijo Aguda eka ti ipinle Sokoto, Bisoobu Mathew Kukah, Kofeso Attahiru Jega to je alaga egbe INEC tele ati onidajo-feyinti Emmanuel Ayoola Babalola.

Gege bi alaga igbimo oludari ile iwe naa, Ojogbon Iyorwuese Hagher se so, o ni awon eniyan ti awon dalola yii lo je awon ti won ti kopa ribiribi ninu idagbasoke igbe aye awon eniyan awujo. Eleyii to se apejuwe won gege bi awon eni iyi ateye.

Alaafin nikan o darin, die lara awon ayaba ati igbimo Oyomesi koworin pelu oba to je nikete ti Gbadegesin Ladigbolu II goke aja. Koda, won tun ya foto pelu awon oloye nigba ti won pada saafin baba ti mbe lode Oyo.

About oodua

One comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*