Home / Àṣà Oòduà / Yorùbá dún

Yorùbá dún

Hà à à!!
Elédùmàrè ìgbà wo
l’ènìyàn yόò to bo nínú hílàhílo òde ayé yìí
nà? Ki baálé ilé jáde láti òwúrò kùtùkùtù àná kό sí ma b’ojú
wéhìn wo, Ǹjé irú ìwà béè daa??
Àmò sà à!! Èyí tà á se sikù,
Ohun owό mi ό to, ma fi gogo fà.
‘modé yìí bami gbe sééré o jare,
‘Sáré tete wá’
Ní í seku Agéége.
Ìràwé kì í dájó ilè kó sùnkè
Onísèépé kò ní í sùnko igi
Kàká kó sunko igi.
A si yè é sílè.
Èrò, bé e délé
E bá mi ki Akíntáyò
E pé, kó sáré tete wá pàdé è mi
Èmi Olámidé l’Ókè-Àró.
(O fi èyí lélè. Ó mú òmíràn. Ó n pofò sí i:)
Idin kò sùn.
Ìdin kò wo.
Eja nlá kì í rójúú gbé ‘bú
Alákàn kì í rójúú gbé’lè odò
Oba tí n lu àgbálùgèdè fOlófin
Kò gbodò sun, kò gbodo wo
Bí Akíntáyò kò bá ri
Èmi Olámidé nínú yàrá yìí
Kò gbodò sùn, kò gbodò wo.
(Ó fi òògùn èyí lélè. Ó tún mú òmíran tí ó jé ìpara, ó
n pofò síi:)
Eku-kéku kì í rùn kò borí asín
Èèrà-kéèrà kì í rùn kó borí ìkamùdù.
Igikígi kì í rùn kó borí ifon.
‘Sè-sè-sè’ ni tègà.
Ojó tíjìímèrè bà fojú kan Alápìn-ín-ni
Lòràn inúu rèé tán
Àfè kì í jé orúko méji.
Bí Akíntáyò yóò bá wí,
Kó wi pé, àfèmi Olámidé
Bí Ayìnla mi yóò bá wí
Kó wí pé, àfèmi Olámidé
Àfè kì í jórúko méji…..
Tό! Tό!! Tό!!!….
Gbogbo èyí ìyàwó ilé to n se’rú èyí, e yami l’étí yín ooo….
Ìwà búrukú o lόrúko méjì, ohun búrukú níí se, ìwo to n f’όgun
b’oko lo pò nínú ilé, ọ̀rẹ́ẹ̀ dákun dáàbò jáwó níbè, kìí sohun to
daa, b’oko o ya dindinrin, a si padà wa d’afofungbemu, Ǹjé
iwúri ni fún ìyàwó ilé todi baálé ‘lé lόjijì? E je ka se’ránti
atúnbòtan, ìwà taa ba hù sílè lόmo wa a de bá, béè kòsí èdá ti
yόò hu’wà ìkà t’Oba mi adake-dajo o ní sésan fún, ìwo ìyàwó
onísééré, se ìrántí atúnbòtan…. (Ààbò òrò)
A kú ojúmó ooo gbogbo omo Oòduà pọ́nbélé, Aaji’re bí??

About Awo

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo