Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí:
(a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́.
(b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́.
(d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́.
(e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́.
(ẹ) A kò fi èdè abínibí wa kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́



