Abiyamo Padanu Omo Re Kan Soso Sinu Agbara Eje
Isele kan to sele lojo Eti to koja yii ni Asaba to wa ni Ipinle Delta je eyi to ba ni lokan je jina.
Arabirin kan, eni odun metadinlogoji (37), Maureen Akowe, la gbo wi pe o padanu omo re eni osu merin bi aja re se koju ija si omo re.
Gege bi iwe iroyin LEADERSHIP ti ile Nigeria to jade lonii, Sande, se so.
Omobirin naa ko omo re, aja ati omoodo ti n ba toju omo sinu moto lati lo re e ra nnkan nile itaja igbalode to wa loju ona Okpanam niluu Asaba.
Igba ti won de ile itaja naa, iya omo jade lati lo ra nnkan ninu ile itaja nigba to fi omo re, omoodo ati aja re sinu moto.
Nibi ti iya omo ti jade lo ra awon nnkan to fe ra ni aja ti fo mo omo tuntun lojiji to si bere si ni fehin san omo naa ni gbogbo ara de ikun ati oju.
Omoodo naa figbe ta fun iranlowo awon eniyan to wa lagbegbe naa sugbon pabo naa ni gbogbo re jasi.
Awon osise alaabo ile itaja pada gbo igbe omoodo naa. Nigba ti won yoo fi sare de idi moto ti ariwo ti n jade, omo osu merin ti won pe oruko re ni Chinonso ni aja ti ba ara re je koja bo ti ye. Inu agbara eje ni won ba omo naa ki won to gbe e jade.
Oju aja to se ise ibi naa ti yi pada. O ti bere si ni se bi aja digbolugi, bee ni i gbo kikankikan bi igba ti kinihun ba n bu ramuramu. Oju re ti ranko bi ti ogidan ololaaju, bee ni ahon re yo lala sita to si n kan eje lenu balabala.
Iya omo naa pada mo nipa isele naa, kete ni won si ti gbe omo naa lo si osibitu to wa loju ona Nnebisi.
Sugbon igba ti won yoo fi de osibitu, omo eje orun alailese lorun naa ti pajude ti ko si le mi mo.
Ohun ti omoodo madaamu so ni yii:
“Madaamu gbe aja naa sinu moto nitori a fe ya gbe aja naa ri dokita eranko. Sugbon nigba ti a de supamakeeti ti madamu fi emi ati aja ati omo sinu moto, sadeede ni aja naa yanu. Eru ba mi. Mo logun pe madaamu, sugbon madaamu ko gbo igbe mi.”
Gege bi iwadii awon oniroyin lowo awon molebi. Won ni odun meta seyin ti arabirin naa ti se igbeyawo ti ko si tete romo bi niyii. Okan soso ti Olorun fun un naa lo ti pada gbe senu aja yii.
Oko omobirin naa soro, bo ti n soro ni ekun kikoro n jade lenu re.
“Iyawo mi ni ise esu ni, esu un gan-an naa ni yoo ti jade nile mi. Mo ti ki i nilo nipa aja un nigba ti mo sakiyesi wi pe awon iwa aja naa ti yi pada. Ko gbo si mi lenu, o si n gbe aja naa kiri. O ni oun yoo gbe lo fun itoju. Se ri aye mi ba yii? O ti fi oriburuku ara re ko ba mi.”
Eemo Lukutupebe….!