Home / Aarin Buzi / Akoni osere onitiata: Bimbo Thomas gbayi!

Akoni osere onitiata: Bimbo Thomas gbayi!

Orisiirisii eniyan lo wa laye pelu agbara inu eleyii ti Oba oke da mo onikaluku won. Eyi ti Oluwa fun Bimbo Thomas lo je eyi to jo mi loju ju. Yato si wi pe Edua oke fun lebun ise tiata sise, omobirin naa je eni to maa n dunnu nigba gbogbo. Kii gba ohunkohun laaye lati ba idunnu re je, yala nipa awon oro ti ko fidi mule ti awon eniyan maa n so nipa awon elere ori itage.
Bimbo je enikan to n maa fi ero okan re han lai beru ohun ti enikeni le so nipa re.

Bimbo rewa lobirin, o si je enikan to nife awon eniyan re gidigidi. O feran oge sise, o si tun so wi pe ife oun si oti waini lo mu oun da ile itaja ti won ti n ta oti waini sile. Bimbo Thomas ni akoni mi fun osu yii. To ba tun ya, maa ma so die sii nipa oba oge, eleyinju ege, onibadi aran, alase ati oludari BIMBALLY Wine & Liquor.

Sugbon sa, ki n to dake, kilode ti sisi naa laiki fesikaapu pupo na?

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...