Home / Àṣà Oòduà / Covid-19 ló sàkóbá fún isé̩ e̩gbè̩rùn kan, ìjo̩ba ìbíle̩ kan – Festus Keyamu

Covid-19 ló sàkóbá fún isé̩ e̩gbè̩rùn kan, ìjo̩ba ìbíle̩ kan – Festus Keyamu

Covid-19 ló sàkóbá fún isé̩ e̩gbè̩rùn kan, ìjo̩ba ìbíle̩ kan – Festus Keyamu
Yínká Àlàbí

Agbejoro agba to n ja fun eto omoniyan to tun je minisita eto ise fun ipinle, Festus Keyamu lo n salaye fun awon oniroyin nipa aseyori Buhari.

Keyamu ni “oro kanle kan baale, yoo kan jeje ni mo jokoo mi”. O ni akoba kekere ko ni ajakale arun coronavirus se fun orileede yii.


O ni ibi ti ijoba kankan ko ronu de ni ijoba Buhari ronu de fun odun merin eleekeji yii. O ni eto ise egberun eniyan ni ijoba ibile kookan ni orileede yii. A si ni ijoba egberin din merindinlogbon (774).

Keyamu ni ijoba si ti seto egberun lona ogun naira fun enikookan losu. O ni eto yii si maa mu banki merin dani, o ni ajosepo awon banki yii lo maa din inawo naa ku.

O ni awon eniyan yii kan maa lo foruko sile ni awon ile ifowo-pamo-si yii. Nomba idanimo (BVN) won ni won fi maa san owo fun won. Eyi ko si tun ni fi aaye ki eniyan kan gbowo eniyan meji dani.


Minisita yii ni ibanuje gidi lo je bi ajakale arun yii se wolu ti ko je ki gbogbo agbaye mo “odo ti won maa da orunla si”.

O ni ju gbogbo re lo, ijoba apapo ko ti da eto gidi naa nu. O ni eto naa si n mumu laya ijoba apapo ti o si maa bere laipe.

About ayangalu

x

Check Also

Sanwo olu

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré Yínká Àlàbí Ile-iṣẹ Aṣẹ ati Iṣakoso Pajawiri ti Ipinle Eko sọ pe awọn ti setan lati dahun si awọn ipe pajawiri ni ipinlẹ Eko laarin isẹju marun-un pere.Olùdarí Àgbà fún ilé-iṣẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Femi Giwa, sọ èyí ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú awọn oniroyin ní ìlú Èkó.Giwa sọ pé àfojúsùn ilé-iṣẹ́ náà ni láti dín àkókò tó wà láàrín ìyè àti ikú kù nípa rírí dájú pé ìdáhùn náà wáyé láàrín ìṣẹ́jú ...