Home / Àṣà Oòduà / Eṣọ́ àjọ FRSC mẹ́ta tí ààrá sán pa gbọdọ̀ ṣ’ètùtù – Ẹlẹ́buùbọn

Eṣọ́ àjọ FRSC mẹ́ta tí ààrá sán pa gbọdọ̀ ṣ’ètùtù – Ẹlẹ́buùbọn

Eṣọ́ àjọ FRSC mẹ́ta tí ààrá sán pa gbọdọ̀ ṣ’ètùtù – Ẹlẹ́buùbọn

Ṣé ọlọ́tọ̀ ní t’óun ọ̀tọ̀, a díá fún òkú tó kú ńlé, tí wọ́n sin s’óko.
Àgbà Imọlẹ̀ kan nlẹ yìí ti fèsì sí ìṣẹ̀lẹ̀ ààrá tó sán láìpẹ́ yìí pa àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ ẹṣọ ojú u pópó mẹta ,o ní,ìkìlọ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ àrá tó sán pa àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojú-pópó (Federal Road Safety Corps) mẹ́ta, tí òp̣ò ̣sì farapa nípìnlẹ̀ Ògùn.

Ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀, Ògbó Awo Yẹmí Ẹlẹ́buùbọn tí tún se Àràbà Òṣogbo tẹnumọ́ ọ bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà pàtì ọ̀hún.

Itele-Ijebu ní Old-gate ni ìsẹ̀lẹ̀ náàt ti ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́rú.

A gbọ́ pé bí àrá yìí ṣe sán ló pa àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́ta náà lójú ẹsẹ̀, tó sì jan àwọn míì mọ́lẹ̀, ti gbogbo agbègbè náà sì di ibùdó erujeje lójú ẹsẹ̀.

Ìròyìn tó tẹ̀wà lọ́wọ́ tún sọ pé àwọn oníṣàngó lọ ṣètùtù tó yẹ, kò tó di pé wọ́n gbé òkú wọn fún ìjọba.

Àmọ́, Àgbà Imọlẹ̀ náà ní ìṣẹ́ kan kìí ṣẹ́ lásán, tí kò bá sì nídìí, obìnrin kìí jẹ́ ikúmólú.

Bàbá Ṣàngó kìí sàdédé pààyàn bẹ́ẹ̀ tí kò bá jẹ́ wípé àwọn èèyàn náà ti ṣe nǹkan àìtọ́ kan.

Bàbá Ẹlẹ́buùbọn ní ó yẹ kí wọ́n ṣe ṣètùtù láti dènà àjálù mìíràn papàá jùlọ àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ àwọn èèyàn tó kú.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo