Minisita fun eto ilera, Ojogbon Isaac Adewole, ti se idaniloju alaye wi pe, efon abami ti n sokunfa kokoro Zika ti ko gboogun ti wa ni Naijiria. Bakan naa lo si ro awon eniyan lati se ohun gbogbo ni ikapa won lati dena efon lati ma fenu kan won lara.
O ni awon eniyan le dena efon Zika yii nipa lilo neeti adena efon (mosquito nets) ni akoko ti won ba fe sun lale. “Ona abayo kan soso to wa bayii ni lilo mosquito nets lati daabo bo ara wa nitori wi pe, ko ti si oogun to le gba eniyan sile lowo arun kokoro Zika apani naa,” Ojogbon se alaye bee niluu Abuja. Bakan naa lo gba awon alaboyun nimoran lati ma rin irin ajo lo awon agbegbe ti Zika ti n se ijamba lowolowo bayii latari ipo elege ti won wa.