Home / Àṣà Oòduà / “Efon ti n fa kokoro Zika wa ni Naijiria, kosi ti gboogun”- Minisita Ilera

“Efon ti n fa kokoro Zika wa ni Naijiria, kosi ti gboogun”- Minisita Ilera

Minisita fun eto ilera, Ojogbon Isaac Adewole, ti se idaniloju alaye wi pe, efon abami ti n sokunfa kokoro Zika ti ko gboogun ti wa ni Naijiria. Bakan naa lo si ro awon eniyan lati se ohun gbogbo ni ikapa won lati dena efon lati ma fenu kan won lara.

O ni awon eniyan le dena efon Zika yii nipa lilo neeti adena efon (mosquito nets) ni akoko ti won ba fe sun lale. “Ona abayo kan soso to wa bayii ni lilo mosquito nets lati daabo bo ara wa nitori wi pe, ko ti si oogun to le gba eniyan sile lowo arun kokoro Zika apani naa,” Ojogbon se alaye bee niluu Abuja.  Bakan naa lo gba awon alaboyun nimoran lati ma rin irin ajo lo awon agbegbe ti Zika ti n se ijamba lowolowo bayii latari ipo elege ti won wa.

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo