Home / Àṣà Oòduà / ERÍWO YÀ! ERÍWO YÀ!! ERÍWO YÀ!!!

ERÍWO YÀ! ERÍWO YÀ!! ERÍWO YÀ!!!

Gbogbo ẹ̀yin Babaláwo àti Oníṣẹ̀ṣe lápapọ̀; Ojú rẹ rèé o : Babaláwo Babájídé Ọ̀ṣúnníyì (Olúwo Jọ̀gbọ̀dọ́ Ọ̀rúnmìlà).

Ní òní yìí ni ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn oyún síṣẹ́ fún ọ̀dọ́mọbìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ padà sí ìdí Ifá / Ìṣẹ̀ṣe (lẹ́yìn ikú Baba rẹ ní bí ọdún mélòó sẹ́yìn) ní èyí tó fẹ́ la ikú òjijì lọ láì ṣe ìtọ́jú rẹ̀ (ní èyí tó jẹ́ ìgbà kẹ̀jọ́ fún ọ̀dọ́mọbìnrin mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) tí ẹgbẹ́ Society for the Ifá Practice in Nigeria (SIPIN) fi kan Babaláwo Babájídé Ọ̀ṣúnníyì alias Olúwo Jọ̀gbọ̀dọ́ Ọ̀rúnmìlà bẹ̀rẹ̀ nílé Awo ilẹ̀ Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ṣùgbọ́n sí ìyàlẹ́nu gbogbo àwọn Olóyè Awo ilẹ̀ Ìbàdàn, Babaláwo Jídé Ọ̀ṣúnníyì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ ìpè Ọ̀ṣẹ́ Méjì ní Ìbàdàn, ó ní ọmọ Ọ̀yán ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni òun, àti pé òun kàn ń gbé; òun sì ń tún ṣe Awo ní ìlú Ìbàdàn lásán ní (bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn ní ìyá tó bíi).

Ilé Awo wá ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé ìdí nìyí tí ó fi fẹ́ ba Ilẹ̀ Ìbàdàn jẹ́ nìyẹn?

Ilé Awo Ilẹ̀ Ìbàdàn wá paá láṣẹ fún un àti fún àwọn ẹbí rẹ̀ láti wá jẹ́ ìpè Ọ̀ṣẹ́ Méjì tí ilẹ̀ Ìbàdàn ní ìtàdógún Awo tó ń bọ̀.

Adérèmí Ifáòleèpin Adérèmí
Founder and Chief Coordinating Officer
Society for the Ifá Practice in Nigeria (SIPIN).

About Awo

x

Check Also

seun kuti

Orí kó Seun Kuti yọ kúrò lọ́wọ́ ikú ní yàrá ìgbàlejò US

Mary Fágbohùn Olórin Afrobeat Seun Kuti ti fi ìrírí ibanuje ọkàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà han nígbà tí ọta ibọn kan gúnlẹ̀ lójú fèrèsé yàrá igbalejo rẹ̀. O salaye ibapade to ba ni lẹru naa lori oju-iwe Instagram rẹ, o fi fidio ferese ti ọta ibọn naa bajẹ ati iho re han. Seun, ẹni ti o ṣalaye iyalẹnu, beere iwoye ti aabo ni Amẹrika. Ninu fonran naa, Seun Kuti sọ pe oun wa ninu yara igbalejo, ti oun n sinmi, ...