Gomina ipinle Oyo, Abiola Ajimobi ti gbe sadankata fun awon eniyan ipinle Oyo fun atileyin ti won se fun un lati segun niwaju ile ejo to n risi awuyewuye eto idibo to waye lojo isegun to koja yii.
Asekagba ejo awuyewuye eto idibo gomina laaarin Ajimobi ati Rasheed Ladoja waye lose tokoja nibi ti ile ejo ti da Gomina Isiaka Abiola Ajimobi ti egbe oselu APC lare gege bi eni ti yoo ma tuko ipinle Oyo siwaju sii gege bi gomina ipinle naa.
Gomina Ajimobi ti dupe lowo awon eniyan ipinle Oyo fun atileyin ti won se fun un. O ni eleyii n se afihan ijoba awon eniyan looto. Ninu oro re lo wi pe, “isegun to waye lojo Isegun fidi re mule looto wi pe ijoba awaarawa ti rese wale. Awon eniyan ipinle Oyo ni agbara mi, awon si ni isegun mi. Mo si fi n da won loju wi pe won ko ni kabamo rara”.
Gomina si fi asiko naa ro Ladoja, oludije lati egbe oselu Accord lati fowosowopo pelu isejoba re lati gbe ipinle Oyo de ebute ogo.
Abiola Ajimobi, eni odun marunlelogota (65) ti fi igba kan je oga agba ati oludari ile ise epo robi, National Oil and Chemical Marketing Company eka ti ile ise Shell Petroleum Nigeria. Leyin bi odun merindinlogbon (26) ti Ajimobi ti n sowo epo robi lojulowo, o fi ise naa sile lodun 2002 lati gbajumo oselu sise loju paali. Odun 2003 ni ipo senato jamo lowo labe egbe oselu AD nigba ti n soju ekun Guusu Oyo.
Odun 2007 ni igba akoko ti Ajimobi yoo du ipo gomina labe egbe oselu ANPP leyin to pari ipo re gege bi senato sugbon ti ko rowo mu ninu eto idibo odun naa.
Ajimobi tun gbiyanju pada lodun 2011 labe egbe oselu ACN, eleyii ti ipo naa si ja mo o lowo. Akotun tun ni eto idibo odun 2015 je fun gomina Ajimobi, nigba ti awon eniyan ipinle Oyo tun pada dibo yan an sipo gomina fun igba keji labe egbe oselu APC. Iyansipo eleekeji re yii je igba akoko ti ipinle Oyo yoo ma yan eniyan si ipo gomina fun igba keji lera won.